O MA ṢE O: AWỌN ỌLỌPAA MẸTA KU S’OD0 NILUU ỌYỌ

Awọn ọlọpaa mẹta kan ti ba omi lọ nilu Ọyọ Alaafin o. Wọn ko somi, wọn si ku sibẹ, bẹẹ awọn ọmọọta ni wọn n le lọ. Ibi ori-afara kan ti ọgbara ti gbe lọ ni popo Balogun ni won ti ba re sinu omi naa, wọn ko si ye e, wọn gbabẹ lọ sọrun ni.

Iwe iroyin Punch ṣalaye pe ni Atiba Police Station lawọn ọlọpaa naa ti wa, awọn ọmọọta kan ti wọn si maa n mugbo lagbegbe naa ni wọn n le lọ. Bi wọn ti n le wọn lọ ni ọkan ninu awon ọmọọta naa to ti mọ adugbo yii daadaa bẹ sinu odo ọhun, n lawọn ọlọpaa yii ti wọn ro  pe nnkan kekere ni ba bẹ tọ ọ, bẹẹ lawọn mẹtẹẹta si ṣe ku sinu omi, ti wọn  ko si ri oku ọmọọta kankan ni tiwọn, nitori awọn ti mọ ọna oju odo yii, wọn si ti mọ bi awọn ti le wẹ ẹ ja.

Awọn ọlọpaa yii wa wọn de Balogun yiii ni o, wọn si kẹfin awọn ọmọọta naa nibi ti wọn ti n fa igbo wọn. Pii pii pii ni wọn fo bọ silẹ lati inu mọto wọn, ti wọn n pe ọwọ ba awọn ọmọọta yii loni-in. Ṣugbọn awọn ọmọọta ti ri wọn, ni wọn ba fọn danu. N lawọn ọlọpaa paapaa ba gba ya wọn.

Aṣe ninu ọgbun ni wọn n tan wọn lọ, nitori loju ibi ti odo naa ti buru ju ni wọn tan wọn gba, bi ọkan ninu wọn si ti bẹ sodo ti awọn ọlọpaa yii tọ ọ, niṣe ni wọn rì sinu ẹrọfọ, nibẹ ni wọn si ti mu omi ku.  Alukoro awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi, sọ pe ootọ lọrọ naa. O ni olobo lo ta awọn ọlọpaa yii pe awọn ọmọọta naa n fẹe dan palapala kan wo, iyẹn ni wọn ṣe gbera lati tete lọọ ko wọn, afi bi wọn ṣe ku somi.

O ni ọwọ awọn  ti tẹ awọn ọdaran naa ṣaa o, bi won si gbọn bii aṣarun, wọn yoo jiya ẹṣẹ wọn.

2 thoughts on “O MA ṢE O: AWỌN ỌLỌPAA MẸTA KU S’OD0 NILUU ỌYỌ

  1. mo daba wipe iroyin naa kun.bo si sele han-an le se se akosile re.afikun to wa nibe nipe inu ira ni ibi ti won pe ni odo yi.o da gege bi eyi ti opo emi ti sofo ni agbegbe Ikejja.ti awon eeyan sa wo inu e.nigba isele ado oloro to dun.afi kolohun maa so wa ka ma gba enu ise denu iku o.ki olohun tu awon ebi won ninu.toripe odomode to sese tewo gbase olopa niwon!

  2. Ki olorun tewon safe rere, kosi to awon ebi won ninu. Odun ni pup Latin gbo iru origin kayefi yi. Olorun yio sima to asiri awon amount sewa lawujo wa. Moki ileise loops pe wonky araferaku

Leave a Reply