O ma ṣe o, ayẹyẹ ọjọọbi Sunny Ade ku ọla, iyawo rẹ ku lojiji

Faith Adebọla

Bi ayẹyẹ ọjọọbi ọdun karundinlọgọrin ti ilu-mọ-ọn-ka agba ọjẹ onkọrin juju nni, Ọmọọba Sunday Iṣọla Adeniyi Adegẹye tawọn eeyan mọ si King Sunny Ade, iba ṣe dun to, o ku ọjọ kan ki ariya naa waye ni iyawo rẹ, Ọnarebu Risikat Adejọkẹ Adegẹye, ku lojiji.

Afẹmọju ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlegun, oṣu kẹsan-an yii, niṣẹlẹ naa waye ni ile obinrin naa to wa lagbegbe Amuwo-Ọdọfin, nipinlẹ Eko.

Ninu atẹjade kan to tẹ ALAROYE lọwọ, Akọwe kansu ijọba ibilẹ Amuwo Ọdọfin, Ẹnjinnia Ṣeyi Ipinlaye, sọ pe aisan ranpẹ kan ti n ba obinrin naa finra ṣaaju iku rẹ yii.

Oloogbe Adegẹye ti figba kan jẹ amofin to ṣoju agbegbe Amuwo-Ọdọfin nileegbimọ aṣofin Eko, oun si ni ondije-dupo si ileegbimọ aṣoju-sofin apapọ l’Abuja.

Ẹnjinnia Ipinlaye sọ pe “ibanujẹ nla ni iku Mama Gẹye, gẹgẹ bawọn ololufẹ rẹ ṣe maa n pe e, jẹ fun awọn eeyan Amuwo-Ọdọfin ati ipinlẹ Eko. A ba Ọba orin Juju, King Sunny Ade, atawọn mọlẹbi Adegẹye kẹdun gidigidi. A ṣadura ki Ọlọrun tẹ oloogbe safẹfẹ rere.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan-an, ni ayẹyẹ ọjọọbi Sunny Ade maa n waye lọdọọdun.

Leave a Reply