O ma ṣe o, eeyan mẹtala padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ lọna Ilọrin si Mọkwa

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Eeyan mẹtala ni wọn padanu ẹmi wọn, tawọn mi-in si farapa yannayanna ninu ijamba ọkọ meji ọtọọtọ to ṣẹlẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lọna marosẹ Ilọrin si Mokwa, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ laarin ọkọ bọọsi meji ti ọkan n bọ lati Eko, ti ekeji si ko awọn to n bọ lati ilu Sokoto kun inu mọto bamu.

Ọkọ bọọsi to ko ero lati Eko ni wọn lo lọọ rọlu ọkọ tirela kan to wa leti titi. Bi ikeji to ko ero Sokoto ṣe fẹẹ pẹwọ fun ọkọ to kọlu tirela naa loun naa fi titi silẹ wọ igbo lọ.

Awọn ero mẹjọ pere la gbọ pe wọn farapa ninu ijamba naa, ti wọn si ti n gba iwosan nileewosan aladaani kan niluu Bode-Saadu.

Ileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin, UITH, la gbọ pe wọn ko oku awọn mẹtala naa lọ.

Ọga ajọ to n mojuto igboke-gbodo ọkọ loju popo, FRSC, ẹka tipinlẹ Kwara, Gbenga Owoade, ṣalaye pe aikiyesara awọn awakọ naa lo fa ijamba ọhun.

O ni awọn mọkanla lo jẹ Ọlọrun nipe loju ẹsẹ ninu ọkan lara ọkọ naa, eeyan meji lo ku ninu ọkọ bọọsi keji. O fi kun un pe awọn mọlẹbi ọkan lara awọn to ku ti waa gbe oku rẹ.

O rọ awọn awakọ lati maa ṣọra ṣe loju ọna naa, ki wọn si maa ni suuru lasiko ti wọn ba n kọja.

Ọwọade ni eeyan ọgọrun-un kan le mẹrindinlogoji, 136, lo ti padanu ẹmi wọn laarin oṣu kin-in-ni, titi de oṣu kẹsan-an, ọdun 2020 loju ọna Ilọrin si Jẹbba, titi de Mokwa.

Leave a Reply