O ma ṣe, o eeyan mọkanla jona ku nipinlẹ Kogi

Monisọla Saka
Ko sẹni to maa ri bi ọpọ eeyan ṣe jona ku, ti awọn ọkọ olowo nla pẹlu ẹru iyebíye ninu awọn mi-in to ṣegbe danu nibi ijamba ọkọ to ṣẹlẹ nipinlẹ Kogi ti ko ni i bomi loju.
Eeyan mọkanla lo ki aye pe o digbooṣe nibi ijamba mọto to waye lagbegbe Ejule-Ochadamu, nibi biriiji Olofu, Ochadamu, nipinlẹ Kogi ọhun,  l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Lasiko tawọn mọto kan gbina lojiji ni awọn mọkanla naa jona ku loju-ẹsẹ, bẹẹ ni eeyan meje ṣi wa lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun bayii pẹlu bi wọn ṣe fara pa yannayanna.
A gbọ pe ọkọ elepo kan lo sọ ijanu rẹ nu, bo ṣe lọọ sọ lu mọ́to mi-in lo gbana loju-ẹse. Ṣugbọn nitori pe awọn ọkọ to wa loju ona ti wọn n lọ pọ lori ila lasiko ijamba naa lo mu ki ina naa maa ran mọ gbogbo awọn ọkọ ti ko ribi tọọnu pada ọhun.
Ki awọn eeyan si too m’ohun to n ṣẹlẹ ọpọ mọto atawọn ero to wa ninu ẹ lo jona gburugburu.
Eeyan mọkanla lo jona ku, nigba ti awọn mi-in fara pa. Bii ogun ọkọ lo jona pẹlu awọn eru olowo nla ti wọn ko, bẹẹ làwọn kaa to fara kaaṣa iṣẹlẹ yii ko lóùnkà.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC, Bisi Kazeem, fi lede lori iṣẹlẹ yii lo ti ṣalaye pe, mọto bii ogun ni iṣẹlẹ ijamba naa ṣẹlẹ si, ọkọ ajagbe kan, tirela to n gbe epo bẹtiroolu kan, mọto ayọkẹlẹ mejila ati ọkada mẹfa.
O ni ninu iwadii tawọn ṣe ni awọn ti mọ pe ohun to ṣokunfa ijamba ọkọ ati ina to ṣẹ yọ ni oju titi to di pa ati ijanu ọkọ ti ko ṣiṣẹ mọ.
Latari iṣẹlẹ ibanujẹ to kan awọn ọkọ bii ogun yii, ọga agba ajọ FRSC, Dauda Biu, ti ke si awọn awakọ atawọn to ni mọto lati maa ṣe ayẹwo ara ọkọ wọn daadaa bi wọn ba ṣe n lọ lati ibi kan si ibomi-in.

Leave a Reply