Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ẹni kan ku, ọpọ fara pa, nibi ijamba ọkọ kan to waye lopopona Kajọla, nijọba ibilẹ Iṣin, nipinlẹ Kwara, lakooko ti ọkọ ayọkẹlẹ kan ati tirela fori sọra wọn.
Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, niṣẹlẹ agbọ-bomi-loju naa waye nigba ti ọkọ ayọkẹlẹ Sharon kan to n ti Abuja lọ siluu Ilọrin gori sọ tirela kan lasiko ti wọn fẹẹ pẹwọ fun koto. Oju-ẹsẹ ni dẹrẹba to wa ọkọ ayọkẹlẹ Sharon yii ku, ti awọn ọmọdebinrin meji si fara pa nibi iṣẹlẹ ọhun.
Agbẹnusọ ajọ NSCDC, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afolabi, sọ fawọn oniroyin pe wọn ti gbe awọn to fara pa lọ si ileewosan olukọni Fasiti Ilọrin, ati ileewosan Gẹnẹra tiluu Omu-Aran, nijọba ibilẹ Irẹpodun, nipinlẹ Kwara, fun itọju to peye. Wọn si ti gbe oku dẹrẹba naa lọ si yara igbooku-si nileewosan ọhun.