O ma ṣe o, ibi ti God’stime at’ọrẹ ẹ ti n pẹja lomi ti gbe wọn lọ l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ṣe nibanujẹ dori awọn eeyan agbegbe Sir Ọlabanji Akingbulẹ Road, Arigbabọla, niluu Ondo, kodo laaarọ kutukutu ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, lori ọrọ awọn gende meji kan ti wọn ṣeesi ku sinu odo ibi ti wọn ti n pẹja.

Awọn to doloogbe ọhun, God’stime James ati ọrẹ rẹ, Boluwaji Akinade, la gbọ pe wọn ku sinu odo kan tawọn eeyan mọ si Arigba, ni nnkan bii aago mẹfa aabọ aarọ iṣẹlẹ naa.

Gẹgẹ ba a fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ẹnikan to ni ka forukọ bo oun lasiiri, o ni ọpọlọpọ igba lawọn mejeeji maa n wa seti odo naa lati pẹja, idi ti tọjọ ta a n sọrọ rẹ yii yiwọ lo ni o si n ṣe awọn eeyan ni kayefi.

O ni bawọn mejeeji ṣe n de eti odo lọjọ yii ni God’stime gba ibi ti àwọ̀n awọn ọrẹ rẹ wa lọ lati lọọ wo o boya o ti pẹja tabi ko i pẹja.

Asiko to n ka awọn yii kuro ninu omi lo ṣakiyesi pe o wuwo pupọ, ti ko si ṣee fa fun un.

Nigba to gbiyanju titi ti ko ri awọn ọhun fa lo pe ekeji rẹ, Boluwaji, lati waa ran an lọwọ ki wọn le jọ fa a jade nitori pe gbogbo ero rẹ ni pe o ṣee ṣe ko jẹ ẹja pupo ni awọn oun ti ko.

Awọn yii ni wọn n fa lọwọ ti ẹsẹ God’stime fi ṣeesi yọ bara, to si fẹẹ ja sinu odo naa, ibi ti ọrẹ rẹ ti n fa a sẹyin, to si n du u ko ma ba ja sinu odo lawọn mejeeji ba kuku ja si i.

Awọn eeyan kan to wa nitosi gbiyanju ati doola ẹmi wọn pẹlu bi wọn ṣe sare lọọ pe ọkunrin Hausa kan wa ko le waa fa wọn jade kí wọn too mu omi yọ. Ṣugbọn gbogbo igbiyanju Hausa ọhun lo ni o pada ja si pabo pẹlu bo ṣe jẹ pe oku awọn mejeeji lo ri fa jade ninu omi.

Loju-ẹsẹ ni wọn ti lọọ fọrọ yii to awọn ọlọpaa tesan Fagun leti, awọn ni wọn si pada waa gbe oku awọn pẹjapẹja naa lọ si mọsuari ileewosan ijọba to wa niluu Ondo.

Ọpọlọpọ awọn to wa lagbegbe ibi ti iṣẹlẹ yii ti waye ni wọn gbagbọ pe ọrọ ọhun ki i ṣoju lasan nitori pe ki i ṣe igba akọkọ ree ti iru nnkan bẹẹ yoo ṣẹlẹ nibi odo naa.

Leave a Reply