O ma ṣe o, ijamba ọkọ gbẹmi eeyan mẹrinla n’Ipetu-Ijeṣa

Ọmọ kekeke mẹfa ati agba mẹjọ ni wọn ku ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ ta a ṣẹṣẹ lo tan yii lagbegbe Powerline, niluu Ipetu Ijeṣa, nipinlẹ Ọṣun.

A gbọ pe mọto meji; Toyota Sienna alawọ goolu to ni nọmba KRD 842 GY, ati mọto nla alawọ eeru to ni nọmba BAU 171 ZE ni wọn jọ wa ninu ijamba naa.

Alukoro ileeṣẹ ẹṣọ oju popo l’Ọṣun, Agnes Ogungbemi, ṣalaye pe ṣe ni awọn mọto mejeeji fẹẹ ya ara wọn silẹ lọna aitọ (wrongful overtaking) ti wahala naa fi ṣẹlẹ.

Loju-ẹsẹ la gbọ pe awọn eeyan mẹrinla naa, ninu eyi ti obinrin mẹfa ati ọkunrin mẹjọ wa, ti ku, koda, ṣe lẹya-ara awọn kan ja jalajala nigba ti eeyan meji si fara pa.

Ogungbemi ṣalaye pe wọn ti ko oku awọn eeyan naa lọ sile igbokuu-si ti Wesley Guild Hospital, niluu Ileṣa, nigba ti awọn meji ti wọn fara pa naa n gba itọju lọwọ.

O waa rọ awọn awakọ lati mọ pe ẹmi ko laarọ, ki wọn wakọ pẹlu suuru lasiko ọdun Ileya yii.

Leave a Reply