Ọlawale Ajao, Ibadan
Alẹ ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, ki i ṣe ojumọ rere fawọn olugbe adugbo Kọlọkọ, nigboro Ibadan, pẹlu bi ile ṣe wo pa ọmọọdun mẹta kan ti wọn pe ni Ajagbe laduugbo naa.
ALAROYE gbọ pe niṣe nile ọhun ṣadeede da wo lulẹ lai fu ẹnikẹni lara ti tẹlẹ.
Gẹgẹ bi aladuugbo ọhun, Alhaja Sariyu Ọlanrewaju, ṣe sọ, o ni nnkan bii aago meje alẹ Satide lawọn gbọ ariwo nla kan bii ẹni pe nnkan ja lulẹ.
“Ibi ti ẹ n wo yii lo kọkọ wo lulẹ. Bi mo ṣe sun mọ’bẹ pe ki n wo nnkan to n ṣẹlẹ ni mo ṣakiyesi pe abala yooku naa n ya bọ lojiji, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe ibi ti ọmọ yẹn sare lọ gan-an nile yẹn wo si. Ibi ti ile fẹẹ wo si lo sa lọ.’’
Ninu ọrọ tiẹ, Abilekọ Nikẹ Ọlanrewaju sọ pe “mo tiẹ gbiyanju gbogbo agbara mi lati doola ẹmi ẹ, ṣugbọn pabo ni gbogbo igbiyanju naa ja si.”
Akọwe ẹgbẹ awọn lanlọọdu agbegbe naa sọ pe bo ṣe jẹ pe ile ọhun lo wo jẹ iyalẹnu fun gbogbo eeyan nitori oun lo tuntun ju ninu awọn ile agbegbe naa pẹlu bo ṣe jẹ pe lọdun 1973 ni wọn kọ ọ. Bẹẹ, aimọye ọdun ṣaaju igba naa ni wọn ti kọ awọn ile yooku lagbegbe ọhun.