O ma ṣe o, iwaju ile Ọlanrewaju lawọn agbebọn pa a si l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti, labẹ idari CP Tunde Mobayọ, ti bẹrẹ iwadii ijinlẹ lati mọ awọn to pa ọdọmọde oniṣowo kan, Ọlanrewaju Ọladapọ,  niluu Ado-Ekiti l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Oloogbe naa lawọn agbebọn kan da ẹmi ẹ legbodo ni nnkan bii aago mẹwaa ku iṣẹju mẹẹẹdogun alẹ ọjọ naa nile ẹ to wa lagbegbe Dallimore, l’Ado-Ekiti.

Ẹnikan to n gbe lagbegbe tiṣẹlẹ ọhun ti waye sọ fun ALAROYE pe agbegbe ọhun naa ni Ọlanrewaju ti n ta kaadi ipe atawọn nnkan jijẹ, bo si ṣe kuro ni ṣọọbu ẹ lo kọri sile. O ni awọn agbebọn naa tẹle e de ile ẹ to wa lẹyin ileewosan kan lagbegbe ọhun, ẹnu ọna gan-an ni wọn si pa a si.

Lẹyin eyi lo ni wọn ko owo atawọn nnkan ini ẹ mi-in ki wọn too ba tiwọn lọ.

Akọroyin wa gbọ pe oṣu diẹ sẹyin ni oloogbe naa ko de ibi ti wọn pa a si yii, iru iṣẹlẹ bẹẹ lo si n sa fun to fi ko wa si agbegbe naa, ṣugbọn o jọ pe awọn to n le e kiri naa lo pada da ẹmi ẹ legbodo.

Ọdọmọde oniṣowo to jara mọ’ṣẹ ni wọn pe Ọlanrewaju nigba aye ẹ, bẹẹ lo jẹ ẹni to bọwọ fun eeyan, ki i ṣe oniwahala rara.

Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti, nipasẹ ASP Sunday Abutu to jẹ Alukoro wọn, ti sọ pe awọn n ṣewadii iṣẹlẹ ọhun lọwọ, awọn si n wa awọn amookunṣika ọhun.

Lasiko ta a pari akojọpọ iroyin yii, mọṣuari ni oku oloogbe wa.

Leave a Reply