O ma ṣe o, Iya Funkẹ Akindele ku lojiji

Asiko yii ki i ṣe eyi to dara fun gbajumọ oṣere ilẹ wa to tun n dije fun ipo igbakeji gomina ipinlẹ Eko ninu ẹgbẹ oṣelu PDP. Eyi ko sẹyin bi iya oṣere naa ṣe ku lojiji.

Ko ti i sẹni to le sọ ohun to ṣokunfa iku iya oṣere yii, ṣugbọn ohun to daju ni pe iku iya yii yoo dun oṣere naa jọjọ, nuitori bo ṣe fẹran rẹ ati bi wọn ṣe jọra wọn bii imumu.

Lọdun to kọja ti iya naa ṣe ayẹyẹ ọjọọbi rẹ, ti oṣere yii si ko awọn ọrọ dundun, ọrọ iwuri nipa iya rẹ pe, ‘Iya mi to dara ju lọ, mo nifẹẹ rẹ. Mo dupẹ fun iṣẹ takuntakun ti ẹ ṣe ati awọn ẹkọ to niyelori ti ẹ kọ mi, ati bi ẹ ṣe jẹ awokọṣe fun mi, eyi to tun aye mi ṣe lati di ẹni ti mo da lonii.

Titi lae ni n oo maa dupẹ lọwọ yin. Mo gbadura pe ki ẹ ṣe ọpọlọpọ ọdun laye.

Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe iya naa pada ku lojiji.

Gbogbo awọn ọrẹ ati alatilẹyin oṣere yii ni wọn n ba a daro, ti wọn n gbadura fun, wọn si n rọ ọ pe ko mu ọkan le. Wọn gbadura pe ki Ọlọrun tu u ninu, ko si tẹ mama naa si afẹfẹ rere.

 

Leave a Reply