O ma ṣe o, moto ọlọpaa tẹ ọga ọlọpaa pa l’Ado-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Inu ọfọ nla ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti wa bayii latari bi ọkọ awọn ọlọpaa ti ẹka Rapid Response Squad (RRS), ṣe tẹ ọga ọlọpaa kan to wa nipo supiritẹndẹnti pa lojiji.

Bakan naa ni ọlọpaa mẹjọ mi-in tun fara pa yannayanna ninu ijamba naa to waye ni Agọ-Adunlojun, l’Ado-Ekiti.

Ọga ọlọpaa ti ẹnikan ko ti i mọ orukọ rẹ yii ni wọn lo wa lori ọkada to n bọ lati agọ Aduloju, to si ṣe kongẹ ọkọ awọn ọlọpa kogberegbe RRS yii nigba ti wọn n le awọn onifayawọ kan loju ọna to lọ si ileewe Poli Ado-Ekiti.

Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Babatunde Mobayọ, fi ṣọwọ sawọn oniroyin l’Ado-Ekiti l’Ọjọruu, Wẹside, lo ti kẹdun pẹlu ọga ọlọpaa  to j’Ọlọrun nipe naa.

Kọmisana yii ṣalaye pe ni deede aago mẹfa aabọ irọlẹ  ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kejila, lawọn ṣadeede gba ipe kan lati Ikọle-Ekiti pe kawọn RRS yii wa mu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti wọn n da agbegbe naa laamu.

Ọga ọlọpaa yii ṣalaye pe bi wọn ṣe gba ipe yii tan ni ọga agba ni ẹka RRS yii paṣẹ pe ki awọn ọmọọṣẹ rẹ maa lọ si agbegbe naa.

Ṣugbọn ohun to jẹ ibanujẹ nibi ọrọ naa ni pe bi wọn ṣe n lọ lọna ni mọto ti wọn n gbe lọ ṣadeede yọnu lọna, to si fo kuro loju ọna, to lọọ pade ọkada to n bọ lọna tirẹ to jẹ eyi ti ọga ọlọpaa yii gun.

Ọga ọlọpaa to ku yii ni wọn sọ pe o ṣẹṣẹ ṣiwọ iṣẹ lọjọ naa, to si n dari lọ sile.

Oju-ẹsẹ ni wọn gbe e lọ si ọsibitu fun itọju, ṣugbọn awọn dokita pada kede pe o ti ku. Bakan naa ni wọn ni mẹjọ lara ajọ RRS yii ni wọn fara pa, ti wọn si ti n gba itọju lọwọ nileewosan awọn ọlọpaa to wa ni Ado-Ekiti.

Leave a Reply