O ma ṣe o, nibi ti alaga kansu Eko tẹlẹ ti n pari ija lo ku si ni Iniṣa

Dada Ajikanje

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ ni ̀ọrọ iku kọmiṣanna nipinlẹ Eko nigba kan, Enoch Ajiboṣo, ṣi n ya awọn eeyan lẹnu. Idi ni pe ọkunrin naa ko saisan telẹ, ọpọ eeyan lo si n sọ pe awọn ri i ni ọjọ diẹ si asiko ti yoo ku yii ti ohunkohun ko ṣe e. Afi bi ọkunrin naa ṣe n ba awọn kan pari ijani aafin ọba Iniṣa, to si digbo lulẹ, to ku ki wọn too gbe e de ọsibitu.

ALAROYE gbọ pe aafin Ọba Iniṣa, Joseph Ọladunjoye,  nijọba ibilẹ Odo-Ọtin, nipinlẹ Ọṣun, ni ọlọjọ de ba Ajiboṣo, ẹni ti wọn pe ni ẹni aadọrin ọdun.

Ọkan lara awọn ọmọ oloogbe naa, Fẹmi Ajiboṣo lo fidi rẹ mulẹ fawọn oniroyin pe ija ni baba naa lọọ pari laarin awọn meji kan, ati pe nibi to ti n pẹtu si aawọ ọhun ni baba naa ti ṣubu lojiji, ti titan si de ba a, ki ẹnikẹni too le ran an lọwọ.

Yatọ si ipo kọmiṣanna fun eto ọgbin ti baba naa di mu, ẹẹmeji ọtọtọ ni wọn lo ti dipo alaga ijọba ibilẹ Agege mu nipinlẹ Eko. Bakan naa la gbọ ọkunrin naa ti ṣiṣẹ nileefowopamọ First Bank laarin ọdun 1980 si 1997.

 

Leave a Reply