O ma ṣe o! Oṣere tiata Yoruba ku lojiji

 Jọkẹ Amọri

Loootọ ni aisan to lagbara da oṣere ilẹ wa kan, Akingbemisọla Dorcas Anjọla, gbalẹ lati bii ọdun diẹ sẹyin, ti gbogbo awọn ololufẹ rẹ si wọle adura fun un. Ki i ṣe pe wọn n gbadura fun un nikan, ọpọ eeyan lo nawọ iranwọ owo si ọmọbirin ti wọn pe ni manija Kesari Productions, to jẹ ti Ibrahim Yẹkinni, ti gbogbo eeyan mọ si Itele, nitori aisan to lagbara lo ṣe e, iyẹn jẹjẹrẹ ile ọmọ ti wọn n pe ni (Ovarian Cancer), eyi ti wọn ni o ti wọ ọ lara gan-an.

Ṣugbọn nigba to dinu oṣu Kejila, ọdun to kọja yii, iyẹn lọjọ ti ọdun naa pari gan-an, ti oṣere naa jade, to gbe fọto rẹ jade, nibi to ti ki awọn oṣere ẹgbẹ ẹ ati gbogbo awọn ololufẹ rẹ, to fi mọ gbogbo awọn to dide iranlọwọ fun un nigba to n saisan, gbogbo eeyan lọkan wọn balẹ, tinu wọn si n dun pe ewu ti fo ọmọbinrin naa ru, aisan to n ṣe e ti lọ. Ohun to tun fi awọn eeyan lọkan balẹ ni nigba ti wọn tun n ri oṣere naa loko ere. Koda, ọpọ ninu awọn ẹgbẹ rẹ ni wọn n sọ pe iyanu Ọlọrun lo gbe e dide.

Ọkan ninu awọn oṣere ẹgbẹ ẹ, Jamiu Azeez, kọ ọ nigba naa pe, ‘Aburo mi daadaa, o jẹ ọkan ninu awọn ẹri to jẹ ki n gbagbọ pe loootọ ni iṣẹ iyanu wa, ati pe loootọ ni Ọlọrun wa. Inu mi dun gidigidi pẹlu bi mo ṣe ri ẹ ti inu rẹ n dun, ti o si n lokun si i lojoojumọ, gbogbo ẹru wa lo ti fo lọ, wa a si lo ọpọlọpọ ọdun si i loke eepẹ ninu ilera pipe ati ọpọlọ ọrọ̀’’.  Bakan naa ni ọrẹ oṣere yii kan kọ ọ sabẹ ọrọ idupẹ to sọ pe oṣere naa ni iyanu oun fun ọdun 2022.

Afi bi wọn ṣe tufọ pe Gbemisọla ku lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, wọn ni aisan jẹjẹrẹ to n ṣe e naa lo pada, ṣe aisan lo si ṣee wo, ko sẹni to ri ti ọlọjọ ṣe, arẹwa oṣere naa faye silẹ, o gba ọrun lọ.

Awọn oṣere ẹgbẹ ẹ ti wọn ba akọroyin wa sọrọ nidakọnkọ, ti wọn ko fẹ ka darukọ awọn sọ pe ọmọbinrin naa ṣe ọkan akin lasiko aisan naa, wọn ni pẹlu bi aisan naa ṣe da a gbalẹ lawọn akoko kan, ọpọ eeyan ni ko mọ, nitori bi ara rẹ ṣe ya diẹ lo jade sita, to si maa n gbe aworan ara rẹ sori Instagraamu rẹ, ti yoo si kọ ọrọ ireti ati iwuri si i. Koda, wọn ni lasiko to wa lori ibusun to n gba itọju lọsibitu, ko bọkan jẹ rara, ẹrin naa lo n rin, pẹlu igbagbọ pe Ọlọrun yoo wo oun san.

Bo tilẹ jẹ pe oṣere to ṣẹṣẹ n dide bọ ni, wọn ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii onirẹlẹ ọmọ, ọpọ awọn oṣere ẹgbẹ ẹ lo si fẹran rẹ  nitori ọyaya to maa n ṣe.

 Latigba ti wọn ti tufọ Gbemisọla ni gbogbo awọn oṣere ẹgbẹ ẹ ti n banujẹ, ti wọn si n daro iku ọmọbinrin ti ko ti i dagba pupọ ọhun. Ọkan ninu awọn oṣere to tun jẹ bii ọga fun Gbemisọla, Ibrahim Yẹkinni, ti gbogbo eeyan mọ si Itele, lo kọkọ tufọ oṣere-binrin naa lori Instagraamu rẹ, nibi to kọ ọ si pe, ‘Allahu Akbar, sinmi ninu alaafia o, Gbemi. O ma ṣe o. Asan ninu asan. To si fi ami ẹni ti ọkan rẹ bajẹ sibẹ.

ALAROYE gbọ pe ọmọọṣẹ rẹ ni ọmọbinrin yii. Yatọ si pe o jẹ ọmọ iṣẹ rẹ, oun lo tun jẹ manija fun ileeṣẹ to fi n gbe fiimu jade, Kesari Productions. Gbemisọla to doloogbe yii kopa ninu fiimu kan ti wọn pe akọle rẹ ni ‘Titled Razor’, eyi ti Itele funra rẹ dari. Bakan naa lo tun wa ninu fiimu ‘Ajifowope’, eyi ti Afeez Abiọdun dari.

Ẹni kan to kọ ọrọ sabẹ ohun ti Itele kọ yii, ade_solaa, sọ pe ‘Ara rẹ si ti n ya o, to ti n lọ si oko ere. O jẹ ẹni kan to nigbagbọ gan-an. Ki Ọlọrun fun ọkan rẹ nisinmi. O jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ lati gbọ.

Bakan naa ni oṣere mi-in, Jamiu Azeez kọ ọ sori Instagraamu rẹ pe, ‘O daarọ o, gbemi, mo koriira ki n maa gbe iru awọn nnkan bayii sori ikanni mi, ṣugbọn eleyii ba mi nibi ti ko dara. Alujanna onidẹra fun ọ, arabinrin mi’.

ALAROYE gbọ pe yatọ si iṣe ere ori itage to n ṣe, oṣere ọmọ bibi Igbọkọda, nipinlẹ Ondo yii, tun n ta awọn pafuumu olooorun didun, ipara atawọn nnkan aṣaraloge bẹẹ bẹẹ lọ.

 

 

Leave a Reply