O ma ṣe o, o ku oṣu meji pere ki ọmọbinrin yii ṣeyawo ni mọto pa a lori ọkada

Faith Adebọla

Ibanujẹ ti dori agba kodo fawọn mọlẹbi ọmọbinrin arẹwa ti ẹ n wo fotọ ẹ yii, tori oṣu meji pere lo ku Immaculate Okochu ko deni ile ọkọ ki ijamba ọkọ to waye lagbegbe Ajah, ni ilu Eko l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii too da ẹmi rẹ legbodo.

Ọmọ bibi Ebu, nipinlẹ Delta loloogbe ọhun, ṣugbọn ilu Eko ni wọn bi i si, ibẹ lo ti kawe, o si gboye jade ni Poli Yabatech. Nigba ti ijamba fi ṣẹlẹ si i yii, maneja ni nileeṣẹ Cold Stone Creamery Limited ni Apapa.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, aṣọ alawọ yẹlo kan ti wọn lo fẹran lọmọbinrin naa wọ jade laaarọ ọjọ tiṣẹlẹ ọhun waye, to dagbere pe oun n lọ sibiiṣẹ, ṣugbọn ko pada wale laaye mọ, ko tiẹ ti i de ibiiṣẹ naa to fi pade iku gbigbona to mu un lọ. Wọn ni tori ati tete de ibiiṣẹ ni Immaculate fi ni ki ọlọkada kan gbe oun siwaju, ori ọkada naa ni ni wọn ni ọkọ akẹru kan ti lọọ kọ lu wọn, to si ṣe oloogbe naa leṣe kọja aala.

Bo tilẹ jẹ pe mọto to kọ lu u yii ko duro, sibẹ awọn to wa nitosi ṣaajo rẹ, oju-ẹsẹ la gbọ pe wọn ti gbe e lọ sọsibitu aladaani kan to wa nitosi, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.

Ohun ta a gbọ ni pe inu oṣu kẹta ọdun yii loun ati ọkọ afẹsọna re lọọ ṣeto ẹngejimẹnti wọn niluu ọmọbinrin naa, oṣu kẹwaa ọdun yii ni wọn si da lati ṣegbeyawo.

Leave a Reply