O ma ṣe o! Olukọ Poli Ibadan padanu ẹmi ẹ sinu ijamba ọkọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Inu ọfọ nla lawọn aláṣẹ ati gbogbo olukọ ile-ẹkọ gbogboniṣe ìjọba ipinlẹ Ọyọ, ìyẹn The Polytechnic, Ibadan, wa bayii pẹlu bi ọkan ninu awọn olukọ ileewe nla naa ṣe pàdánù ẹmi ẹ sinu ìjànbá mọto lọna Isẹyin.

Olukọ naa, Akitẹ́ẹ́kì Kọla Ọladujoye, to ti figba kan jẹ olórí ẹka ti wọn ti n kọ nipa ilẹ̀ wíwọ̀n pẹlu awọn mẹta mi-in ni mọto wọn ko sinu Odo Ògùn, lọna Isẹyin, nigba tí ọkọ wọn nijamba nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Lati ibi ipade kan ti won lọọ ṣe ninu ọgbà ileewe Oke-Ogun Polytechnic, to wa niluu Ṣaki, la gbọ pe wọn ti n bọ ti ìjànbá ọhun fi waye.

Olukọ Poli to doloogbe yii lo gbe awọn mẹta yooku ti wọn jọ rìnrìn-àjò naa sinu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ. Niṣe ni mọto ọhun gbokiti lati ori afara bọ sinu odo naa.

Ọladunjoye nikan lo j’Ọlọrun nipe loju-ẹsẹ, nigba ti awọn mẹta yooku wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Agbẹnusọ Poli Ibadan, Alhaji Ṣọladoye Adéwọlé, ṣàpèjúwe oloogbe naa gege bíi ọkan ninu awọn onimọ ijinlẹ nileewe ọhun nigba to wa laye.

Leave a Reply