O ma ṣe o, terela Dangote tun pa baba atọmọ ẹ ni Lọkọja

Ọrọ terela Dangote to paayan ni ipinẹ Ogun ni lọsẹ to kọja lawọn eeyan ṣii n tori ẹ kawọ mọri, omi-in ti tun ṣẹlẹ ni Lọkọja, ipinlẹ Kogi nirọlẹ ana o.

Terela Dangote kan lo tun n bọ ni adugbo Soonu-eeti (Zone 8), ṣugbon ere buruku lo n ba bọ. Igba to de ikorita kan to ni ki oun yi ọwọ mọto biri, bi kinni naa ṣe lọ́ mọ ọn lọwọ niyẹn, lo ba ya bara, lo gba ibi ti awon eeyan wa lọ. N lọrọ ba di igbẹ-la-a-fẹwe, oko-la-a-wa-nnkan-ọbẹ, kaluku sa asala fun ẹmi rẹ. Ere lẹlẹ!

Ṣugbọn baba kan to n lọ to ko ọmọ rẹ meji dani ko ṣe bẹẹ ribi sa gba, terela Dangote yii mu oun ati ọmọ rẹ kan, loju ẹsẹ lo si ti ran wọn sọrun. N lawọn araalu ba binu, wọn ko si jẹ ki terela naa ribi gba, awọn naa dana sun un. Ṣugbọn ‘terela kan wa to ẹmi baba atọmọ bi?’ Ohun tawọn ọogbọn n beere ree, iyẹn n iwon s iṣe n pariwo e opki ijoba tete wa nnkan ṣe si ọrọ awọn terela Dangote yii o.

Leave a Reply