O ma ṣe o, tirela Dangote tẹ eeyan mẹta pa l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ẹni ti ko ba le ṣe ọkan akin ko le wo oku awọn eeyan mẹta kan ti tireta Dangote tẹ pa lalẹ ọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii, nibi ti wọn dubulẹ gbalaja si l’Ago-Oko, l’Abẹokuta!

Ori ọkada lawọn eeyan mẹta naa wa, ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ni gẹgẹ bi Babatunde Akibiyi, Alukoro Trace, ṣe sọ.

O ni ọlọkada to ko ero meji sẹyin naa fẹẹ ya tirela Dangote to wa lapa ọtun rẹ silẹ ni, nibi to ti fẹẹ sare kọja naa ni ọkada mi-in ti n bọ lẹyin rẹ, o si gba a siwaju, bo  ṣe gba wọn sabẹ tirela to fẹẹ ya silẹ niyẹn.

Ẹsẹkẹsẹ ti eyi ṣẹlẹ lawọn eeyan mẹtẹẹta to wa lori ọkada akọkọ jẹ Ọlọrun nipe, tirela tẹ wọn. Foonu kan ti wọn ri lara ọkan ninu wọn ni wọn fi pe awọn eeyan wọn ti wọn fi waa gbe oku wọn lọ.

Akinbiyi tilẹ sọ pe niṣe lawọn ọmọọta sọ iṣẹlẹ aburu naa di nnkan ole jija, o ni wọn ko ẹru to wa ninu tirela Dangote naa lọ. Koda, wọn le awọn ọlọpaa ati TRACE paapaa danu, wọn pitu ọwọ wọn wọ alẹ gbere ni.

Leave a Reply