O ma ṣe o, wọn ba oku iya pẹlu awọn ọmọ rẹ meji ninu ṣọọbu

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ ohun to ṣokunfa iku iyaale ile kan ti ko sẹnikankan to mọ orukọ rẹ, ẹni ti wọn ba oku rẹ ati tawọn ọmọ rẹ mejeeji kan ninu ṣọọbu kan to wa lagbegbe PPL, ni Ijagun, niluu Okokomaiko, nijọba ibilẹ Ọjọ, nipinlẹ Eko.

ALAROYE gbọ pe ohun ti awọn eeyan ti wọn n gbe lagbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye sọ ni pe o ṣee ṣe ko jẹ eefin jẹnẹratọ ti wọn gbe sinu ṣọọbu naa lalẹ ọjọ ti wọn fẹẹ sun sinu ṣọọbu naa lo ṣokunfa iku iya at’ọmọ ọhun. Ṣugbọn awọn kan n sọ pe o ṣee ṣe ko je pe ṣe lawọn eeyan naa jẹ majele mọnu ounjẹ ti wọn jẹ lalẹ ọjọ naa.

Ọgbẹni kan to n gbe lagbegbe nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ to ba akọroyin Punch sọrọ, ṣugbọn ti ko fẹẹ daruko ara ẹ sọ pe oorun buruku kan bayii to n jade lati inu ṣọọbu  tawọn eeyan naa ku si lo mu ifura wa, ti wọn si jalẹkun ṣọọbu naa mọ wọn lori. Nibẹ ni wọn ti ri oku iyaale ile naa atawọn ọmọ rẹ mejeeji yii nibi ti wọn fọrun kọ si, ti wọn si ti wu gelete.

Loju-esẹ lawọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Ọjọ, nibi ti iṣẹle naa ti ṣẹlẹ, ti gbe oku wọn kuro ninu ṣọọbu naa, tawọn mọlẹbi wọn ti won wa nitosi si ti sinku wọn ni ilana ẹsin Musulumi.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinle Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin sọ pe oun paapaa ti gbọ si iṣẹle naa, ati pe awọn olọpaa yoo ṣiṣẹ lori ọrọ ọhun ki wọn lẹ mọ eyi ti i ṣe ootọ lori iku iyaale ile naa.

Leave a Reply