O ma ṣe o! Akẹkọọ Fasiti LAUTECH ja sinu sọkawee, lo ba ku patapata

Ọlawale Ajao, Ibadan

Waiwai ni inu ọgba Ladoke Akintọla University of Technology (LAUTECH), to wa niluu Ogbomọṣọ da bayii pẹlu bi ọkan ninu awọn akẹkọọ wọn nibẹ ṣe jin sinu sọkawee, to si gbabẹ lọ sọrun aremabọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ ta a lo tan yii.

Igbesẹ yii lo ṣakoba fun awọn ayẹwo to yẹ ko waye laarin awọn akẹkọọ ẹka kan nileewe naa, bẹẹ ni ko si idanilẹkọọ kankan to waye nibẹ titi ti ilẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, fi ṣu.

Ki i ṣe oju bọrọ lọgba ile ẹkọ nla naa ṣe da paroparo bẹẹ bi ko ṣe nitori iwọde ti awọn akẹkọọ ṣe lọsan-an-an ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹrin, ọdun 20201 yii, ti i ṣe ọjọ Ẹti, Furaidee, lati fi aidunnu wọn han si ọna ti akẹkọọ ẹgbẹ wọn ọhun to n jẹ Asefon Nifẹmi Benard gba riku ojiji he.

Benard, ẹni ti iba gboye gẹgẹ bii akẹkọọ-jade fasiti lọdun yii, ni wọn lo deede ja sinu sokawee nibi to ti n kọja lọ nirọlẹ ọjọ kejilelogun, oṣu kẹrin, ọdun 2021, ti i ṣe Ọjọbọ, Tọsidee.

Akitiyan awọn ẹgbẹ ẹ lati doola ẹmi ẹ ko seso rere pẹlu bo ṣe jẹ pe o ti gbẹmi-in-mi  ki wọn too ri oku ẹ yọ ninu koto to kun fun igbọnsẹ naa.

Gegẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, inu ọkan ninu awọn ilegbee ti awọn akẹkọọ LAUTECH n gbe niṣẹlẹ ọhun ti waye. Idi ree tawọn akẹkọọ fasiti naa fi binu ṣewọde ninu ọgba ileewe yii lati fi adiunnu wọn han si awọn alakooso ileewe naa, wọn ni bi wọn ṣe dagunla si atunṣe sọkawee yii lo jẹ ko jin mọ akẹgbẹ awọn lẹsẹ, to fi ja sinu koto to sọ ọ dero ọrun alakeji.

Ninu atẹjade ti Ọmọwe Kayọde Ogunlẹyẹ ti i ṣe Akọwe agba fasiti yii fi ṣowọ sawọn oniroyin, o ni igbimọ awọn alaṣẹ ileewe ọhun ti ranṣẹ ibanikẹdun sawọn obi atawọn akẹgbẹ oloogbe naa.

Wọn ni ki i ṣe ninu ọgba fasiti ọhun ni Benard ku si. Bẹẹ ni wọn rọ awọn akẹkọọ naa lati fọwọ wọnu, ki wọn si ma ṣe fi itara iku akẹgbẹ wọn yii gbe igbesẹ to le ṣakoba fun ẹmi eeyan, tabi ba dukia kankan jẹ.

Leave a Reply