O ma wa ga o, wọn tun pa ọmọ ọdun mẹrindinlogun mi-in l’Akinyẹle, n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Niṣe ni gbogbo eeyan ro pe iku ojiji tawọn olubi ẹda kan fi n pa awọn eeyan ni ijọba ibilẹ Akinyẹle, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, yoo mọwọ duro pẹlu bi ọwọ ọlọpaa ṣe tẹ awọn kan ti wọn jẹwọ pe awọn lawọn wa nidii ọrọ naa, ti wọn si foju wọn han lọsẹ to kọja. Ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ pẹlu bi awọn kan ṣe tun lọọ pa ọmọbinrin ẹni ọdun mẹrindinlogun kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Tokẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni Akinyẹle yii kan naa.

ALAROYE gbọ pe adugbo Onikoko, loju ọna Ibadan si Ọyọ, ni awọn ọlọpaa Moniya ti kan oku ọmọdebinrin naa ninu igbo lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ ta a wa yii.

Epo bẹntiroolu ni wọn ni awọn obi ọmọ yii ni ko lọọ ra wa lalẹ ọjọ Aje, ti wọn ko si ri i ko pada sile ki wọn too lọọ kan oku ẹ ninu igbo yii.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Chuks Enwonwu, ti ni ki iwadii bẹrẹ lori awọn to ṣiṣẹ buruku naa.

 

Leave a Reply