O ma waa ga o, awọn agbebọn tun pa ọlọpaa mẹta, wọn dana sun teṣan wọn

Kaka kewe agbọn dẹ, niṣe lo n le koko si i lọrọ iṣẹlẹ itajẹsilẹ, pipa ọlọpaa ati didana sun dukia to n waye lapa Guusu ilẹ wa, wọn lawọn agbebọn naa tun ṣeku pa awọn ọlọpaa mẹta lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde yii, ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa Nsukwa, nipinlẹ Delta, wọn si dana sun ileeṣẹ naa.

Ba a ṣe gbọ, ọsan gangan, ni nnkan bii aago kan, ọjọ Sannde ọhun lawọn janduku rẹpẹtẹ naa ya bo olu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Nsukwa, nijọba ibilẹ Guusu Aniocha, nipinlẹ ọhun.

Ẹnikan tiṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ sọ pe ko sẹni to mọ ibi tawọn agbebọn naa gba yọ, ojiji ni wọn de, ariwo gee la kan n gbọ, keeyan si to mọ ohun to ṣẹlẹ, wọn ti da ibọn bolẹ, onikaluku si bẹrẹ si i sa kijokijo.

Wọn ni bawọn agbebọn naa ṣe de lawọn ọlọpaa teṣan ọhun ti gbọna ẹyin sa lọ, ṣugbọn awọn ọlọpaa mẹta ti wọn wa niwaju teṣan naa ko raaye sa, lawọn agbebọn naa ba dana ibọn ya wọn, wọn si pa wọn loju ẹsẹ.

Wọn lawọn ẹruuku naa tun ko gbogbo ibọn ati ọta to wa ni teṣan naa, wọn ja ilẹkun ahamọ, ṣugbọn ko sẹni to le sọ ohun to ṣẹlẹ si ọdaran kan to wa lahaamọ boya wọn pa a, tabi wọn tu u silẹ ni.

Wọn ni fun bii wakati kan ni iro ibọn n dun ni kọṣẹkọṣẹ, ko si sẹni to yẹ awọn eeyan naa lọwọ wo ti wọn fi pari ọṣẹ buruku wọn.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Delta, CP Ari Ali, ni oun ti gbọ nipa iṣẹlẹ yii, ṣugbọn oun ko le sọ ohunkohun lori rẹ. Bakan naa ni Ọgbẹni Bright Edafe, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Delta ni iwadii ṣi n lọ lọwọ.

Leave a Reply