O ma waa ga o, wọn tun ṣa iya oniyaa ladaa pa l’Akinyẹle, n’Ibadan

 Ọlawale Ajao, Ibadan

Nigba ti ọkan awọn ara Akinyẹle, n’Ibadan, ti balẹ pe ọwọ awọn agbofinro ti tẹ awọn afurasi ọdaran to n pa awọn eeyan nipakupa kaakiri adugbo awọn, ti alaafia si ti jọba lagbegbe naa, biri lọrọ tun yi lojiji nigba tawọn ẹruuku tun ṣa iya kan ladaa pa lagbegbe yii kan naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Iya ọhun, Abilekọ Oluwafunmilayọ, ni wọn lọọ ka mọle ẹ to wa laduugbo ti wọn n pe ni Ori Oke-Ọlọrunkọle, l’Akinyẹle, n’Ibadan, ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ti wọn si ṣa a ladaa yannayanna.

Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii oṣu kan aabọ sẹyin, iyẹn ninu oṣu kẹfa si ibẹrẹ oṣu keje, ọdun 2020 yii, lawọn ọbayejẹ eeyan ti fi ada ati ṣọ́bìrì ṣa eeyan bii mẹwaa pa.

Bo tilẹ jẹ pe awọn iranṣẹ iku wọnyi ko ri Abilekọ Oluwafunmilayọ pa lẹsẹkẹsẹ nigba ti wọn ba a lalejo lalẹ ana, nitori ti awọn alabaagbe ẹ sare gbe e lọ sọsibitu nigba ti wọn gbọ to n keboosi irora, irora oju ọgbẹ nla ọhun lo pada pa a nibi ti wọn ti n tọju ẹ lọwọ nileewosan UCH ti wọn gbe e lọ fun iwosan.

Nitori bi awọn ẹlẹ́gírí ti ṣe pa ọpọ eeyan nipakupa nijọba ibilẹ Akinyẹle ṣaaju lẹnu ọjọ mẹta yii, pẹlu ibinu lawọn ọdọ agbegbe naa fi ya sigboro laaarọ yii (Furaidee) lati fẹhonu han.

Awọn ọdọ wọnyi fibinu kọ lu agọ ọlọpaa ijọba ibilẹ naa to wa ni Mọniya, n’Ibadan, wọn ṣe awọn ọlọpaa kan leṣe, bẹẹ ni wọn ba nnkan jẹ ni teṣan naa.

Bakan naa la gbọ pe wọn ba awọn nnkan jẹ lawọn ibomi-in lagbegbe ọhun ko too di pe awọn ọlọpaa adigboluja da wọn lẹkun Ibinu.

Nigba to n fidi iṣelẹ yi mulẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, fi aidunnu eẹ han si bi awọn ọdọ ṣe lọọ kọ lu agọ ọlọpaa agbegbe naa, o ni bi iwọde wọn ọhun ṣe la yanpọnyanrin lọ ko tọna rara.

O waa fi da gbogbo araalu loju pe laipẹ lọwọ awọn agbofinro yoo tẹ awọn ọdaju eeyan to ṣeku pa iya oniyaa naa, nitori awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply