O ma waa ga ọ! Wọn tun ji agbẹ mi-in gbe n’Igangan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ọjọ mẹta ti wọn ji gbajumọ oniṣowo epo rọbi gbe niluu Idere, nitosi Igboọra, nipinlẹ Ọyọ, ki wọn too pada yinbọn pa a, wọn tun ti ji ọkunrin agbẹ kan, Nosiru Aderoju, gbe niluu Igangan, nipinlẹ yìí kan naa.

Ta o ba gbagbe, lọsẹ to lọ lọhun-un ni wọn ji agbẹ kan tó n jẹ Oluwọle Agboọla gbe ninu oko ẹ lọna Ibadan siluu Ọyọ.

Ni nnkan bíi aago mẹjọ aabọ alẹ lawọn ajinigbe ọhun lọọ ka Alhaji Aderoju mọ itosí ile ẹ, ti wọn sì gbé e bii igba ti aṣa ba gbe ọmọ adiẹ.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, lasiko ti ọkunrin agbẹ náà n dari lọ sile lẹyin to kí irun aago mẹjọ alẹ tan lawọn amookunṣika ẹda naa lọọ da a lọna, ti wọn si ji i gbe nitosi ilé ẹ l’Oke Agbẹdẹ, niluu Igangan.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, alaga ẹgbẹ idagbasoke ilu Igangan, Ọgbẹni Ọladokun Ọladiran, sọ pe o jọ pé awọn obayejẹ ẹda naa ti n ṣọ Ọgbẹni Aderoju tipẹ, ti wọn sì n tẹle e kiri tẹlẹ ki wọn too papa ri i mu.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Awọn eeyan ṣakiyesi awọn àjèjì kan bíi Fulani ni mọṣalaṣi ti Aderoju ti kirun lalẹ ọjọ yẹn, ṣugbọn wọn ko fura pe iṣẹ ibi ni wọn waa ṣe. O ṣee ṣe ko jẹ pe awọn èèyàn yẹn ni wọn ṣọ ọ dé mọṣalaṣi ki wọn too tun ti ibẹ tẹle e de ọna ile ẹ ti wọn ti jí i gbe.

 

Agbẹnusọ fún ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, fidi iṣẹlẹ yìí mulẹ, o ni awọn agbofin ti bẹrẹ iṣẹ lati yọ ọkunrin agbẹ naa kuro nigbekun awọn ajinigbe ọhun, ki wọn sì mú awọn afurasi ọdaran naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Awọn ẹbi ẹni ti wọn ji gbe yẹn ko fi iṣẹlẹ yẹn to ọlọpaa leti, ṣugbọn ba a ṣe hu u gbọ, ta a sì fidi ẹ mulẹ ni Ọga agba ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Joe Nwackukwu Enwonwu, ti da awọn ọlọpaa si gbogbo awọn ibi kọlọfin to ṣee ṣe ki awọn afurasi ọdaran yẹn fara pamọ si.

Pẹlu ogo Ọlọrun, a máa mú àwọn tó ṣiṣẹ yẹn, a sì máa gba ẹni tí wọn ji gbe silẹ lọwọ wọn.”

Leave a Reply