O n rugbo bọ: Awọn agbebọn ji awọn ọmọleewe ati tiṣa gbe l’Edo

Faith Adebọla

Titi di ba a ṣe n sọ yii, ko ti i sẹni to le sọ pato iye awọn akẹkọọ ati tiṣa ileewe ẹkọṣẹ ikọle ati imọ ẹrọ, National Institute of Construction Technology tawọn janduku agbebọn lọọ ji gbe loru mọju Ọjọbọ, Tọsidee yii, nipinlẹ Edo. Bawọn kan ṣe n sọ pe akẹkọọ meji ati tiṣa kan ni, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe wọn ju bẹẹ lọ.

Iṣẹlẹ yii waye leyii ti ko ti i ju ọjọ meji lọ ti ẹgbẹ ajafẹtọọ ilẹ Yoruba kan, Apapọ Oodua Kọya (AOKOYA) sin awọn gomina ilẹ Yoruba ni gbẹrẹ ipakọ pe olobo ta awọn pe awọn agbebọn ti fẹẹ maa ji awọn ọmọleewe gbe lawọn ipinlẹ Yoruba kan.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni lati nnkan bii aago mọkanla aabọ oru Ọjọruu lawọn agbebọn ti wọn ya bo ileewe naa ti ṣina ibọn bolẹ, ti eyi si da jinnijinni bo awọn ọlọdẹ, akẹkọọ ati tiṣa to n gbe inu ọgba ileewe naa.

Ẹnikan to ba Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) sọrọ lori iṣẹlẹ yii sọ pe o ju wakati kan lọ ti wọn fi yinbọn, inu ibẹrubojo lawọn aladuugbo naa wa, o ni itosi ileewe naa loun n gbe.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo, SP Bello Kotongs, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn o ti i le sọ pato iye ẹni ti wọn ji gbe ati ibi ti wọn ji wọn gbe lọ, ṣugbọn loootọ lawọn agbebọn jiiyan gbe loru mọju yii.

O lawọn agbofinro ti bẹrẹ si i tọpasẹ awọn agbebọn naa, ki wọn le da awọn ti wọn ji gbe naa silẹ lominira lai farapa.

Leave a Reply