O ṣẹlẹ: Alaga APC kọwe fipo silẹ l’Ondo, lo ba darapọ mọ PDP

Alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nijọba ibilẹ Ẹsẹ Odo, nipinlẹ Ondo, Samuel Ọlọrunwa, ti kọwe fipo silẹ.

Ọlọrunwa fipo silẹ gẹgẹ bii alaga, bẹẹ lo kuro ni APC patapata.

Iroyin to tẹ wa lọwọ bayii ni pe o ti lọ si ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP) lati lọọ ba igbakeji gomina Ondo, Agboọla Ajayi.

Leave a Reply