O TAN! ARUN KORONA TI MU MINISITA BUHARI O

Ọkan ninu awọn minisita ti wọn n ba Aarẹ Muhamadu Buhari ṣiṣẹ ninu jjọba rẹ yii ti ko arun korona o. Minisita fun ọrọ ilẹ okeere ni, Godfrey Onyeama. Oun funra ẹ lo jẹwọ pe kinni ọhun ti gbe oun.

Minisita naa kọ ọ bayii sori ẹrọ ikede twitter rẹ pe: “Mo ṣe tẹẹsi korona (Covid-19) mi lanaa ni gbara ti mo ti ri i pe ọna ọfun mi gbẹ. o si n ṣe bakan. Esi ayẹwo naa ti pada de bayii o, o si ṣe ni laaanu pe mo ti ko kinni ọhun. Bi ọrọ ile aye ti ri naa niyẹn: ko bọ si i nigba kan, ko ma bọ si i nigba kan. Mo ti wa lọna ile adagbe bayii nileewosan kan, pẹlu adura pe n o bọ nibẹ.

Leave a Reply