Awọn ọlọdẹ yari l’Ọṣun, wọn lawọn o ba Amọtẹkun ṣiṣẹ papọ mọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ọlọdẹ nipinlẹ Ọṣun, (Hunters Group of Nigeria, Osun State Chapter) ti kede pe kaka ki ekute ẹṣọ Amọtẹkun ṣe akapo ẹkun awọn, ki onikaluuku rọra ṣe ọdẹ rẹ lọtọọtọ latari iyanjẹ ọlọkan-o-jọkan ti oju awọn ti ri.

Alakooso ẹgbẹ naa l’Ọṣun, Nurein Hammed, lo sọrọ yii fawọn oniroyin niluu Oṣogbo l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii. O ṣalaye pe owo ẹgbẹ naa to to miliọnu marundinlọgbọn naira ni awọn adari ikọ Amọtẹkun ko jẹ.

Hammed ṣalaye pe lasiko igbele Koronafairọọsi to waye lọdun to kọja ni aparutu naa ṣẹlẹ lai tiẹ wo bi awọn ṣe n fi ẹmi ṣiṣẹ fun aabo awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun.

O ni awọn ko lee ṣiṣẹ papọ labẹ awọn alakooso Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun mọ nitori pe iyanjẹ naa ti pọ ju, ṣugbọn awọn ko ni i dẹkun igbogun-ti ẹnikẹni to ba fẹẹ da omi alaafia ipinlẹ yii ru.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ẹgbẹ wa yoo maa tẹsiwaju lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ikọ alaabo to ku l’Ọṣun lati gbogun ti awọn kọlọransi, tori ohun ti a ti bura lati ṣe ni, ṣugbọn a ko le ṣiṣẹ yii labẹ awọn Amọtẹkun.

“Lasiko igbele Korona ati ti iwọde EndSars, ọpọlọpọ awọn aala ipinlẹ yii la daabo bo, ti a si ri i pe alaafia jọba kaakiri ipinlẹ Ọṣun.

“Lopin gbogbo rẹ, ijọba ipinlẹ Ọṣun gbe miliọnu lọna mẹrinlelogoji naira kalẹ fun wa gẹgẹ bii ọkan lara awọn to wa labẹ Amọtẹkun, ṣugbọn miliọnu mẹẹẹdogun naira pere la ri gba.

“Ẹni to jẹ alakooso nigba naa ṣi wa lara awọn alakooso Amọtẹkun, nitori naa, a ko nigbagbọ kankan ninu wọn mọ lati ba wọn ṣiṣẹ papọ nitori iṣẹ wa gba ka fi ọkan kan ṣiṣẹ.”

Gbogbo igbiyanju wa lati gbọ ti ẹnu alakooso Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Ajagun-fẹyinti Bashir Adewinbi, ni ko so eso rere nitori ko gbe ipe lori foonu rẹ.

Leave a Reply