O tan! Buhari koju ija si Pasitọ Adeboye

Aderounmu Kazeem

Aarẹ Muhammadu Buhari ti kilọ fun olori ijọ Ridiimu, Pasitọ Adeboye atawọn mi-in ti wọn n sọ pe, atunto eto iṣejọba Naijiria lo dara ju lasiko yii pe ki won ṣọra won gidigdi o, ki won si yee fi ọrọ atunto ijọba halẹ mọ oun, tabi ba oun lorukọ jẹ.

Ninu ọrọ ti Ọgbẹni Garba Shehu, oluranlọwọ fun Buhari nipa eto iroyin, fi sita lorukọ Aarẹ orilẹ-ede yii lo ti sọ pe gbogbo eeyan to ba n beere fun atunto iṣejọba lasiko yii, ọta Naijiria niru wọn, bẹẹ ni ijọba yii ko ni i foju rere wo wọn. Bẹẹ lo fi kun un pe, ki kaluku lọ ṣọra, nitori ijọba Buhari ko ni atunto kankan to fẹẹ ṣe lasiko yii.

O fi kun un pe, “Ko sẹni to le ti ijọba Buhari nitikuti, bẹẹ lẹnikan, tabi akojọpọ awọn eeyan kan ko le mu ijọba yii ṣe ohun ti yoo lodi si ifẹ awọn ọmọ Naijiria ti wọn to igba miliọnu ti Buhari n dari, ati pe ohun to jẹ ijọba yii logun julo lasiko yii ni bi opin yoo ṣe deba arun koronafairọọsi, ti itọju awọn ọmọ Naijiria paapaa si ṣe pataki si ijọba Muhammed Buhari.

Tẹ o ba gbagbe, nibi ipade kan ti Ṣọọsi Ridimu ṣe, ni Pasitọ E.O Adeboye, olori ijọ naa ti sọ pe, o ṣe pataki ki atunto ba eto iṣejọba Nigeria, ti a ko ba fẹ ki orilẹ-ede yii fọ si wẹwẹ.

Nibi akanṣe eto ti ijọ ọhun gbe kalẹ lati fi ṣami ayẹyẹ ọgọta ọdun ominira Naijiria, ti wọn pe akọle ẹ ni, Nibo ni Naijiria yoo wa lọdun 2060 lo ti sọrọ ọhun.

Adeboye fi kun un pe o ṣe pataki ki Naijiria ni ọna kan pato ti yoo maa gba fi ṣe ijọba awọn eeyan rẹ, eyi ti yoo jẹ ti orilẹ-ede yii gan-an dipo lilo tawọn orilẹ-ede mi-in, ti kinni ọhun ko si gbe wa debi kankan.

O ni, ṣaaju asiko yii la ti kọkọ lo eto iṣejọba ilẹ Gẹẹsi, nigba to tun ya la mu ti orilẹ-ede America, bẹẹ ni Naijiria ko tori ẹ kuro loju kan.

Ṣiwaju si i, Adeboye ti sọ pe, ti ijọba ko ba tete ṣatunto si eto iṣakoso, o ṣee ṣe ki Naijiria fọ gẹgẹ bawọn kan ti ṣe n wi i. O ni, ohun meji la ni bayii, yala ki a ṣatunṣe ati atunto si eto iṣakoso tabi ka pin, ki kaluku maa ba tiẹ lọ.

Bo tilẹ jẹ pe o gba a ladura wi pe, Ọlọrun ko ni i jẹ ki Naijiria o pin, sibẹ, o ti ni ki awọn oloṣelu ṣe ohun to tọ, ati pe awọn ti wọn n sọ pe ki Naijiria pin ko dara to, bẹẹ lo jọ pe wọn ko mọ ohun ti wọn n sọ ni, nitori iṣọkan ẹ lo yẹ ko jẹ kaluku logun.

Ojiṣẹ Ọlọrun yii ti waa rọ awọn oloṣelu wa lati ṣagbekalẹ eto ijọba to maa ni aarẹ, ti yoo tun ni olori ijọba pẹlu.

O ni, ti a ba le ṣe eyi, ọkan yoo maa ran ikeji lọwọ, bẹẹ ni ayipada rere yoo tọ Naijiria wa.

Ọrọ ti Adeboye sọ ree, n ni Buhari atawọn ọmọlẹyin ẹ ba gba a, ti wọn si bẹrẹ si halẹ kiri wi pe, awọn yoo ṣe ṣege fẹni to ba sọ pe awọn fẹ atunto kan lori eto iṣakoso Naijiria.

9 thoughts on “O tan! Buhari koju ija si Pasitọ Adeboye

  1. Aare yi koni eto kankan fun orile ede yi rara, iro ni won fi ojoojumo pa fun wa, afi ki olorun gbawa lowo ijoba amunileru, biiti Nigeria

  2. Sé ìlú ni Naijariya tàbí ìlù
    Ìlú Awon alayebaje
    Ìlú Awon aláìmòkan
    Ìlú Awon Apanisafé
    Ìba díè lókùn
    Aógbarawa lówó Awon ōníjegúdújerá,
    Àwon àgbàyà ōníranù,
    Àwon adàgbàmádanú
    Adórunmòtító gbogbo.

  3. Buhari maa to te.
    Mo lero wipe ko gbo Iran oba Nebukadinesari abi?
    Abi o to gbagbe iku ogbeni abacha ni?
    Olorun maa to fi titobi re han buhari at awon songbe re laipe.
    Won maa fi ibinu olorun ki odun yii to pari.

Leave a Reply