O tan, Fẹmi Fani Kayọde ti pada sinu ẹgbẹ APC o

Gomina ipinlẹ Kogi, Yahyah Bello, ti kede pe Oloye Fẹmi Fani-Kayọde, ti pada sinu ẹgbẹ oṣelu APC bayii.

Lọjọ kẹwaa, ọsu keji yii, ni iṣẹlẹ ọhun waye lẹyin igba ti Amofin Fẹmi Fani-Kayọde, ẹni ti i ṣe ọkan pataki ninu awọn oguna gbongbo inu ẹgbẹ oṣelu PDP fi awọn eeyan ẹ silẹ, to si ba awọn APC to maa n fi gbogbo igba bu tẹlẹ lọ.

Ninu ọrọ Gomina ipinlẹ Kogi, Yahyah Bello, lo ti sọ pe gẹgẹ bii iṣẹ ti ẹgbẹ APC gbe le oun lọwọ lati maa fa awọn eeyan wọnu ẹgbẹ, inu oun dun lati kede pe Oloye Fẹmi Fani-Kayọde ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu awọn bayii, awọn yoo si jọ maa tukọ ẹgbẹ naa ni.

Ohun to foju han bayii ni pe ọkunrin ọmọ Ile-Ifẹ yii ko ba awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Ọlọburẹla ṣe mọ, ẹgbẹ Onigbaalẹ lo fẹẹ maa ṣe tiwọn bayii, bo tilẹ jẹ pe ọta ẹgbẹ naa lo n ṣe tẹlẹ.

Yahyah fi kun un pe lara awọn to da ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọdun naa lọhun-un ni Fani Kayọde, ati pe ̀ọrọ lo ṣe bii ọrọ to fi fi ẹgbẹ ọhun silẹ lọọ darapọ mọ ẹgbẹ mi-in.O ni Fẹmi to darapọ mọ ẹgbẹ ọhun bayii ni ipa nla to fẹẹ ko lati mu ilọsiwaju ba ẹgbẹ naa ni.

Sa o, Fẹmi Fani Kayọde ko ti i sọ ohunkohun lori igbesẹ tuntun yii, paapaa sori ikanni abẹyẹfo ẹ.

Awọn iroyin tuntun to ko jọ sibẹ lasiko ti a n kọ iroyin yii ni fọto oun ati Gomina Yahyah Bello, ati eyi toun ati Aarẹ tẹlẹ, Goodluck Ebeble Jonathan jọ ya lasiko ti oun pelu awọn eeyan ẹ ṣabẹwo si i niluu Abuja.

Bẹẹ gẹgẹ ni fọto oun ati Alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Gomina ipinlẹ Yobe, Mai Buni, naa wa lori ikanni abẹyẹfo ẹ pẹlu.

 

 

Leave a Reply