O tan! Iwe ti wọn fi pe Tinubu lẹjọ pe o kowo jẹ ti jona ni kootu

Aderounmu Kazeem

Iroyin kan to tun gba ilu kan bayii ni pe iwe ipẹjọ ti wọn fi wọ Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lọ sile-ẹjọ lori ọrọ owo kan ti wọn l mọ bo ṣe poora ti jona o.

Ẹni kan to ti jẹ olori ileeṣẹ Alpha Beta, ileeṣe awọn Tinubu to n ba ijọba Eko gba owo ori lọwọ awọn eeyan, lo fẹsun kan Tinubu pe awọn owo nla nla kan wa to ko jẹ nileeṣẹ naa, bẹẹ lo si n fi ileeṣẹ awọn yii lu ijọba ipinlẹ Eko ni jibiti, ti oun gan-an ko si san owo ori to yẹ ko san. Nitori ẹ lo ṣe lọ sile ẹjọ, paapaa nigba to ni wọn ti le oun kuro nileeṣẹ ọhun ki oun ma baa tu aṣiri ohun to n lọ.

Lasiko ti rogbodiyan ṣẹlẹ lọsẹ to kọja ni ALAROYE gbọ pe wọn sọ ina si kootu, ile-ẹjo giga, ni Igboṣere nibi ti wọn ti fẹẹ gbọ ẹjọ ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan okunrin Jagaban.

Gbogbo kootu ọhun lo jona pata, iwe ipẹjọ ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan Aṣiwaju Bọla Tinubu si wa lara ohun to ṣofo nibẹ, ṣugbon awọn to pẹjọ ọhun ti sọ pe awọn ko ti i dẹyin lẹyin ẹ. Wọn lo di dandan ki awọn ba a fa nile-ẹjọ mi-in laipẹ yii.

Kootu Igboṣere gan an ni wọn gbe ẹjọ ọhun lọ, iroyin to si gbalu ni pe, awọn janduku kan ti sọna si i nigba ti rogbodiyan gbalu kan lọse to kọja.

Ọgbẹni Tade Ipadeọla, ẹni ti i ṣe agbẹjọro fun Ọgbẹni Dapọ Apara, ọga agba nileeṣẹ Alpha Beta nigba kan lo sọrọ ọhun. Ohun to si sọ ni pe, o ti dandan ki Tinubu foju wina ofin nitori loootọ lo ko owo nla jẹ nileeṣẹ ọhun, awọn yoo si ba a fa a daadaa.

Lara ẹsun ti Apara fi kan Bọla Tinubu ni pe lati ọdun 2002 ni ọkunrin oloṣelu yii ti n ko owo rẹpẹtẹ kuro lapo ijọba Eko, to si n da a sapo ara ẹ.

O ni ile-ẹjọ la n duro de bayii, ti wọn ba ti ke si wa, o ti di dandan lati gbe ẹjọ ọhun dide pada ni kootu giga kan n’Ikẹja, nibi ti ọkunrin oloṣelu naa yoo ti ṣalaye gbogbo ohun to ba mọ nipa gbogbo ẹsun ta a fi kan an.

Leave a Reply