O tan, ọmọ ‘Yahoo’ ko ba pasitọ n’Ileefẹ

Idowu Akinrẹmi, Ikire

Ajọ to n ri si iwa magomago ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, EFCC, ẹka tipinlẹ Gombe ti nawọ gan Pasitọ Gbenga Moses ti ṣọọṣi rẹ wa n’Ileefẹ, ipinlẹ Ọṣun, pẹlu ọmọdekunrin kan toun n ṣe jibiti ori ayelujara ti wọn n pe ni ‘Yahoo’ torukọ tiẹ n jẹ Adebayọ Ọlawale, wọn ni wọn lu jibiti miliọnu mejila ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin(12.7m) naira.

Ẹnikan torukọ ẹ n jẹ Umar Hayatu, toun n gbe ni Lafia, nipinlẹ Gombe, ni ALAROYE gbọ pe Adebayọ Ọlawale bẹrẹ si i ba sọrọ lori ẹka Fesibuuku, to n sọ fun un pe baba oun ni ileeṣẹ nla kan niluu oyinbo, o si fẹẹ da iru ẹ silẹ niluu Eko, o n wa ẹni ti yoo ba a ṣe maneja ileeṣẹ naa.

Ọmọ Yahoo yii fi ye Hayatu pe oun yoo ba a ṣe e ki baba oun le gba a sileeṣẹ tuntun naa gẹgẹ bii maneja. N lo ba n sọ fun un pe ṣugbọn oore toun fẹẹ ṣe fun un naa ki i ṣe ọfẹ o, nitori owo nla nla ni yoo maa gba tiṣẹ ba bọ si i tan, koda, awọn aworan ile ati mọto arumọjẹ lo fi n han ọmọ Hausa naa lori ayelujara, to n sọ fun un pe awọn ohun ti ileeṣẹ naa yoo gbe fun un gẹgẹ bii maneja niyẹn to ba ti bẹrẹ iṣẹ.

Eyi lo fa a to fi ni ko maa fowo ranṣẹ soun toun yoo fi ba a ṣeto iṣẹ nla naa, iyẹn si n sanwo fun un loootọ, ko mọ pe gbaju-ẹ lasan ni ọmọkunrin naa n ṣe foun.

Nigba ti aṣiri Adebayọ tu tan, owo to le ni miliọnu mejila  ni wọn ba lakanti ẹ. Ibi to ti kan Pasitọ Gbenga ni tiẹ ni pe wọn lo gba mọto BMW kan, pulọọti ilẹ kan ati ọpọlọpọ owo lọwọ ọmọ ‘Yahoo’ yii, lara owo tiyẹn gba lọwọ Hayatu si ni.

Ni bayii, awọn mejeeji ti wa lakolo EFCC, wọn si lawọn yoo foju wọn bale-ẹjọ lẹyin iwadii awọn.

Leave a Reply