O ti doju ẹ bayii o: ‘YORUBA GBỌDỌ FI NAIJIRIA SILẸ DANDAN!’

Akintoye ati awon aṣaaju Yoruba lo sọ bẹẹ

Awọn ọmọ Yoruba yoo kuro lara Naijiria, kinni naa ko si ni i pẹ rara. Awọn agbaagba Yoruba ni wọn n sọ bẹẹ, bẹẹ ni ki i ṣe ẹni kan ninu wọn, ki i ṣe ẹni meji tabi mẹta. Ohun kan naa ni wọn n tẹnu mọ, iyẹn naa ni irẹjẹ ati awọn iwa buruku mi-in ti wọn n hu si Yoruba ni Naijiria, eyi to si le ju lẹnu ọjọ mẹta yii ni ti awọn Fulani ti wọn n wa gbogbo ọna lati gba ilẹ Yoruba, to si da bii pe ijọba yii n ti wọn lẹyin lati ṣe ohun ti wọn fẹẹ ṣe.

Loju awọn agbaagba Yoruba, bii ẹni pe awọn ti wọn n ṣejọba lọwọlọwọ bayii, paapaa Aarẹ Muhammadu Buhari, ti pinnu lọkan ara wọn pe awọn yoo gba ilẹ Yoruba fawọn Fulani ni, ati pe ko si ohun ti ẹni kan le ṣe si i. Ohun to fa a ti awọn agba Yoruba fi pe birikoto ree, ti wọn si bẹrẹ eto, ti wọn n sọ pe awọn yoo ṣe ohun gbogbo lati ri i pe Fulani ko mu awọn eeyan awọn lẹru, ati pe awọn ko ni i laju silẹ ki ijọba Buhari fa ilẹ Yoruba le awọn Fulani lọwọ, ọrọ naa yoo kan di wahala rẹpẹtẹ ni.

Ọjogbọn Banji Akintoye, ẹni ti i ṣe olori ẹgbẹ ‘Yoruba World Congress’, apapọ ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba, pẹlu awọn agbaagba ilẹ kaaarọ-oo-jiire mi-in, titi dori awọn aṣaaju Afẹnifẹre, Baba Reuben Faṣọranti ati Ayọ Adebanjọ, ni wọn ti figba kan wi pe ko si bi wọn yoo ti ṣe e, bi nnkan ba n lọ bo ti wa yii, Yoruba yoo maa ṣe tirẹ lọtọ ni. Ọsẹ to kọja yii ni wọn ṣe ayẹyẹ iranti Ogun Kiriji, ogun to gun ju lọ ni gbogbo agbaaye, ogun ti wọn fi ọdun mẹrindinlogun ja ni ilẹ Yoruba, to si jẹ ko tun si ibi ti wọn ti ja ogun to pẹ to bẹẹ yẹn ni gbogbo aye. Ọdun 1886, ninu oṣu kẹsan-an, ọdun naa, ni ọjọ kẹtalelogun, ni gbogbo awọn jagunjagun ilẹ Yoruba ati awọn ọba wọn jokoo, ti wọn tọwọ bọ iwe adehun pe ko sogun mọ, ko si ọtẹ mọ, ki gbogbo ọmọ Yoruba wa ni iṣọkan. Lati ọjọ naa ni Yoruba si ti wa niṣọkan wọn. Ọsẹ to kọja ni wọn ṣe ayẹyẹ iranti ọdun naa n’Ibadan, ohun to si bori ọrọ nibẹ naa ni bi Yoruba yoo ti ṣe kuro lara Naijiria kiakia.

Iba Gani Adams

Ọjọgbọn Akintoye ni ko si bi a oo ṣe duro ni Naijiria ki iya si maa jẹ wa, ko maa jẹ awọn ọmọ wa, o ni asiko ti to fun Yoruba lati kuro lara Naijiria, nitori ilẹ yii ko gbe awọn ọmọ Ọodua rara. Nijọ naa lo fi ọkan gbogbo eeyan balẹ pe bi awọn Yoruba ti fẹẹ kuro ni ara Naijiria yii, ko ni i si ogun tabi itajẹsilẹ kan, nitori awọn ko ni i jẹ ki ẹnikẹni ba Yoruba jagun, bẹẹ ni Yoruba ko si ni i ba awọn mi-in jagun, wọọrọwọ ni wọn yoo ṣe gbogbo nnkan, ti Yoruba yoo fi le maa lọ ni tiwọn. Bo tilẹ jẹ pe Ibadan lo ti sọ ọrọ yii, lati origun mẹrẹẹrin agbaye, nibi ti awọn ọmọ Yoruba wa, lati Amẹrika titi yika ilu oyinbo gbogbo, ni wọn ti n sọ pe ododo ọrọ ni, ti kakuku si n sọ pe awọn ti gbaradi, Yoruba yoo kuro labẹ Naijiria ṣaa ni. Ọrọ naa ki i ṣe kekere rara, lojoojumọ lo si n gbilẹ si i.

Bẹẹ ki i ṣe pe kinni naa ṣẹṣẹ bẹrẹ, o ti ṣe diẹ ti awọn aṣaaju Yoruba ti n pariwo pe ohun to n ṣẹlẹ si awọn ni Naijiria ko dara, awọn ko fẹ bi ijọba apapọ ti maa n jẹ awọn eeyan awọn niya, nipa gbigba owo lọwọ wọn fun awọn ara Oke-Ọya, ati ṣiṣe awọn eto kan to jẹ ifasẹyin ati ipalara lo mu ba awọn Yoruba yikayika. Akintoye paapaa ṣalaye iru awọn ọrọ yii nigba kan. Baba naa ni laarin ọdun 1952 titi de 1966, ko si orilẹ-ede kan ni Afrika ti ko da Yoruba mọ gẹgẹ bii aṣaaju, bẹẹ naa si lawọn oyinbo ni Britain mọ pe orilẹ-ede nla kan ati ẹya nla kan ni awọn Yoruba yii i ṣe, gbogbo ohun ilọsiwaju pata, nilẹ Yoruba lẹ o ti ri i. Nilẹ Yoruba yii ni wọn ti kọkọ tan ina ijọba, nilẹ Yoruba yii ni wọn ti kọkọ ṣe biriiji, nilẹ Yoruba yii ni wọn kọko da banki silẹ si, nilẹ Yoruba yii ni wọn ti kọkọ ni ileewe ati awọn oju titi kaakiri. Ko si nibomi-in.

Ilẹ Yoruba yii ni ile iwosan akọkọ wa, ibẹ ni ile-ẹjọ wa, awọn dokita, awọn lọọya, awọn adajọ, awọn aṣiro-owo ati awọn mi-in gbogbo, ilẹ Yoruba yii leeyan yoo ti ba wọn. Laarin ọdun ta a n wi yii, laye ti awọn Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ n ṣejọba, ilẹ Yoruba yii ni wọn kọ ile to ga ju lọ ni gbogbo Afrika nigba naa si, Cocoa House ti awọn Awolọwọ kọ si ilu Ibadan ni. Ijọba yii naa lo kọkọ kọ papa iṣere nla to jẹ ilu oyinbo nikan leeyan ti le ri i, ijọba ilẹ Yoruba yii naa lo kọkọ kọ yunifasiti tirẹ, awọn ni wọn kọkọ ṣeto ile fawọn oṣiṣẹ ọba, bẹẹ awọn naa ni wọn kọkọ gbe tẹlifiṣan de ilẹ Afrika. Gbogbo ohun to ṣẹlẹ yii pata, ni ilẹ Yoruba ni, awọn ọmọ Yoruba funra wọn ni wọn si n ṣe e. Ohun to fa eyi ni pe ọtọọtọ ni ijọba ti wọn n ṣe ni agbegbe kaluku: awọn Hausa n ṣe ijọba tiwọn lọtọ, awọn Ibo n ṣe ijọba tiwọn lọtọ, onikaluku n nawo adugbo rẹ bo ti fẹ ni.

 

Sunday Igboho

Ṣugbọn lojiji ni awọn ologun gbajọba, ti wọn si yi ofin Naijiria pada, wọn ko gbogbo wa sabẹ ijọba apapọ, ijọba apapọ lo si ku to n ṣeto inawo. Wọn tun waa ṣe eto naa debii pe ninu ijọba apapọ yii, awọn ẹya Hausa-Fulani ni wọn lagbara ju lọ. Nidii eyi, awọn ni wọn n ṣejọba, bo jẹ ijọba awọn ṣọja ni o, bo si jẹ ti awọn alagbada. Lati igba ti wọn ti n ṣejọba yii lo jọ pe ifasẹyin ti ba ilẹ Yoruba, ti awọn eeyan ibẹ ko si le da gbe kinni kan ṣe mọ, nitori ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe, afi ki ijọba apapọ Naijiria fọwọ si i. Nibi ti  awọn ijọba apapọ yii ba si ti ni awọn n fọwọ si i, wọn yoo fi ọgbọn da eto naa ru, tabi ki wọn tilẹ ni ko ṣee ṣe. Ṣugbọn pẹlu bi gbogbo eleyii ṣe n lọ, bẹẹ ni wọn n pa owo gidi lati agbegbe ilẹ Yoruba, owo ti wọn ba pa yii naa ni wọn yoo si pin lọdọ ijọba apapọ. Awọn ti wọn ko si pa owo to tilẹ Yoruba yoo si gbowo ju wọn lọ, paapaa awọn ti ilẹ Hausa. Eleyii dariwo kari, nigba ti yoo si di ọdun 2014 ariwo naa ti le gan-an ni.

Ọrọ naa di ariwo to jẹ niṣe ni ijọba to wa lori aga nigba naa, ijọba Goodluck Jonathan, ṣeto ipade apero, nibi ti wọn ti ni ki gbogbo ẹya pe jọ lati waa sọ ohun ti wọn ba fẹ, paapaa awọn ti wọn leri pe awọn fẹẹ lọ. Wọn ṣe ipade apero naa, ohun ti wọn si fẹnu ko le lori ni pe ki wọn ṣe atunto si ofin Naijiria, ki wọn pada si ijọba ti wọn lo laarin ọdun 1952 si 1966, ki agbegbe kọọkan maa nawo ti wọn ba pa, ki wọn si maa ṣeto idagbasoke wọn funra wọn. Gbogbo ofin yii ni wọn jokoo ti wọn tun ṣe, ti gbogbo awọn aṣaaju lati ilẹ Hausa, lati ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo si ṣe. Ṣugbọn ijọba Jonathan ko ri aaye sọ awọn aba ti wọn da nibi apero naa di ofin titi ti wọn fi gba ijọba naa lọwọ wọn, ti Buhari si di olori orilẹede yii tuntun ni 2015. Ṣugbọn nigba ti Buhari de, wọn kọyin si abajade apero yii, wọn ni ko sohun to jọ bẹẹ, awọn ko si fọwọ kan an rara.

Ohun to waa tubọ mu ki ọrọ naa di ibinu tuntun ni pe gbogbo ohun ti wọn sọ ni apero yii pe wọn ko gbọdọ ṣe mọ, awọn ohun ti ijọba Buhari bẹrẹ si i ṣe niyi. Akọkọ ni kiko awọn ẹya kan si ipo nileeṣẹ ijọba apapọ ju awọn ẹya mi-in lọ, ẹẹkeji ni gbigba owo awọn ẹya mi-in lorukọ ijọba apapọ ati pinpin owo naa ni ọna aidọgba (ka maa fun awọn ti wọn ko pawo lọdọ wọn lowo ju awọn ti wọn pawo lọdọ tiwọn lọ). Yatọ  si eyi, ijọba Buhari gbe ofin dide lati gba ilẹ awọn ẹya mi-in yikayika fun awọn Fulani onimaaluu, ọrọ naa si di wahala gidi. Lẹyin ti eyi ko ṣee ṣe, ijọba naa tun ni awọn yoo gba gbogbo bebe omi pata fun ijọba apapọ, awọn aṣaaju Yoruba yii sọ pe gbogbo eto ti awọn ijọba yii n ṣe, lati gba gbogbo ilẹ awọn fun Fulani ni. Bakan naa ni awọn Fulani n ya wọ ilẹ Yoruba, ti ijọba Buhari ko si da wọn lẹkun, bo tilẹ jẹ iwa janduku ni wọn n hu.

Awọn bii Aarẹ Ọna Kakanfo, Iba Gani Adams ti pariwo lori eleyii, ati awọn iwa awọn Fulani titi, ọsẹ to kọja yii ni ajafẹtọọ Yoruba kan, Sunday Igboho, ko awọn agbofinro lẹyin lati lọọ le awọn Fulani jade ninu igbo agbegbe Kiṣi, l’Ọyọọ, ti wọn fara pamọ si. Iwa awọn Fulani wọnyi si n mu aibalẹ-ọkan ati ijaya gidi ba awọn ọmọ Yoruba agbegbe gbogbo.  Gbogbo eleyii lo mu ki awọn agbaagba Yoruba yii sọ pe asiko ti to wayii, Yoruba ko ṣe Naijiria mọ o. 

7 thoughts on “O ti doju ẹ bayii o: ‘YORUBA GBỌDỌ FI NAIJIRIA SILẸ DANDAN!’

Leave a Reply