O yẹ kawọn DSS tọrọ aforiji lọwọ Igboho ni, nitori ki i ṣe ọdaran- Wọle Ṣoyinka

Gbajugbaja onkọwe ilẹ wa nni, Ọjọgbọ Wọle Ṣoyinka, ti bu ẹnu atẹ lu ijọba atawọn ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n wa Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Igboho. Baba naa ni ko yẹ ki wọn sọ pe awọn n wa ọkunrin yii, niṣe lo yẹ ki wọn tọrọ aforiji fun awọn iwa ti wọn hu si i.

Ṣoyinka sọrọ yii ninu iọfọwerọ kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ BBC Pidgin ni Mọnde, ọjọ Aje, ọsẹ yii.

O ṣalaye pe ki i ṣe ohun to bojumu ki awọn ẹṣọ alaabo naa sọ bi Sunday Igboho ṣe n beere fun ‘Oodua Nation’ gẹgẹ bii ẹṣẹ tabi iwa arufin, nitori ko si ẹṣẹ ninu ki eeyan sọ pe oun ki i ṣẹ ara orileede kan tabi pe eeyan fẹẹ darapọ mọ orileede mi-in.

Bẹẹ lo ṣapẹẹrẹ awọn orileede ati agbegbe mi-in ti wọn ti fi orileede wọn silẹ, ti wọn si lọọ darapọ mọ orileede mi-in.

Ọjọgbọn naa bu ẹnu atẹ lu bi awọn ọtẹlẹmuyẹ ṣe lọ si ile Sunday Igboho niluu Ibadan, ti wọn si ba gbogbo ibẹ jẹ. O ni eyi to buru ju nibẹ ni ipa ti ijọba ko lori ọrọ yii pẹlu bi wọn ṣe sọ pe awọn ibọn ti wọn ba nile rẹ fi han pe o n mura lati ba Naijiria jagun ni. Ṣoyinka ni ede naa lagbara diẹ, bii igba ti wọn si fẹẹ doju ọrọ to wa nilẹ ru ni.

Baba naa ni ki i ṣe Igboho nikan lo ti n pariwo lati ọjọ yii wa lori bi wọn ṣe n pa awọn agbẹ, ti wọn si n gbẹmi awọn alaiṣẹ kaakiri Naijiria.

‘Bi Igboho ba tilẹ waa ni awọn ogun ija yii gẹgẹ bi ijọba ṣe sọ, ohun to sọ ni pe gbogbo erongba oun ni lati tu awọn eeyan oun silẹ lọwọ awọn Fulani aninilara ti wọn ti jẹ gaba le wọn lori, ti wọn si n pa wọn nipakupa, ti awọn eeyan ilu naa ko si ri aabo to to lati ọdọ awọn agbofinro, to si jẹ pe kaka ki wọn mu awọn ti wọn ṣẹ, awọn alaiṣẹ ni wọn n mu ti mọle. Iru ẹ naa lo ṣẹlẹ niluu Ibarapa laipẹ yii, nibi tawọn ọlọpaa ti mu awọn to lọọ koju awọn ti wọn n dunkooko mọ wọn niluu naa, ti wọn n fipa ba awọn obinrin wọ lo pọ.

‘Nisinyii tawọn ijọba wa n sọ pe awọn ohun ija yii tumọ si pe Igboho fẹẹ dana ogun ninu ilu jẹ ohun iyalẹnu. Imọran ti mo fẹẹ gba ijọba ni pe ki wọn yee le Igboho kiri gẹgẹ bii ọdaran, nitori bii ọdaran lawọn paapaa ṣe n huwa.’

Ṣoyinka fi kun un pe ijọba lo maa jẹbi ti wọn ba gbe Igboho lọ sile-ẹjọ. Bẹẹ lo bu ẹnu atẹ lu bi wọn ko ṣe maa pe awọn Fulani darandaran to gbe ibọn kiri ni ọdaran. O ni ṣe lo yẹ ki wọn tọrọ aforiji lọwọ rẹ, ki wọn sọ fun un pe aṣiṣe lawọn ṣe, ko yẹ kawọn huwa bi wọn ṣe huwa si i yii, ko waa maa lọ sile rẹ.

Leave a Reply

//eephaush.com/4/4998019
%d bloggers like this: