O yẹ ki Aarẹ Buhari ko awọn igbimọ alaṣẹ rẹ wa ka jọ waa bẹ Yeye Ọṣun lori arun Korona ni- Ọṣunbiyii

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lati igba ti ayẹyẹ ọdun Ọṣun Oṣogbo to waye lopin ọsẹ to kọja ti ku ọjọ mẹta nijọba ipinlẹ Ọṣun, nipasẹ Kọmisanna fun ọrọ aṣa ati ibudo igbafẹ, Dokita Ọbawale Adebisi, ti kede pe ko ni i si aaye fun ipejọpọ gẹgẹ bo ṣe maa n waye lọdọọdun.

Ọbawale sọ pe ko si aaye fun ayẹyẹ kankan latari bi iye awọn to n lugbadi arun Koronafairọọsi ṣe n fojoojumọ gbẹnu soke nipinlẹ Ọṣun. O ni ijọba fẹ ki awọn eeyan ṣe ọdun naa ninu ile wọn, awọn eeyan perete tijọba ba si gba laaye ni wọn yoo lanfaani lati lọ si oju-odo Ọṣun.

Ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ rara, lati nnkan bii aago meje aabọ aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja ti wọn ṣe aṣekagba ọdun naa lawọn eeyan ti n wọ lọ soju odo kẹti-kẹti pẹlu aṣọ funfun ati oniruuru ike omi ti wọn gbe lọwọ. Koda, ọpọ ninu wọn ni wọn ko lo ibomu tabi iboju, bẹẹ ni ko si si pe a n lo sanitaisa rara.

AKEDE AGBAYE bọ saarin awọn eeyan lati beere idi to fi da bii ẹni pe wọn ko bikita fun ẹmi ara wọn, ti wọn tun fi ṣe lodi si aṣẹ tijọba fi lelẹ lori ayẹyẹ naa, iyalẹnu ni esi ti onikalukuu wọn fọ si jẹ.

Ọgbẹni Toriọla Kazeem sọ pe loootọ loun mọ pe arun Korona wa, nitori ọpọ eeyan loun mọ niluu Eko ti oun n gbe ti wọn ti ko arun naa, ṣugbọn bi ijọba ko ṣe loootọ nipa arun naa lo n bi oun ninu. O ni awọn mẹkunnu nikan ni wọn n ka lọwọ ko lati ṣe oun to wu wọn, ofin wọn ko mu olowo.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ti ẹ ba de ibi ti awọn oloṣelu yii ba ti n ṣenawo, boya ọjọọbi tabi oku, ẹ maa ri i pe wọn kan n tan ara wọn ni, wọn ko bọwọ fun ofin ti wọn fọwọ ara wọn ṣe. Ọdun Ọṣun Oṣogbo wa de, wọn n kede pe ka ma waa ṣọdun, ni nnkan to jẹ pe ẹẹkan pere ni lọdun, alẹ ana lemi wọlu lati Eko, mo si tun n pada loni-in ti mo ba ti ṣadua tan, ti mo si bu omi’.

Ajọkẹ Ọṣunbiyi ni tiẹ sọ pe ṣe lo kan wu ijọba lati maa sọ nnkan ti wọn fẹ, ko si ẹni to le di oun lọwọ lati ṣọdun iya oun. O ni “Ṣebi wọn kan n tan ara wọn ni, ṣe ẹyin naa o ri nnkan to ṣẹlẹ nibi ipolongo ibo awọn ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ Edo, gbogbo awọn adari wa ni wọn wa nibẹ o, gbogbo telifisan lo ṣafihan rẹ bo ṣe n lọ, meloo ni Korona ti waa lu pa ninu wọn?

“Ọdun to yẹ ki Aarẹ Buhari gan-an funra rẹ ko awọn igbimọ alaṣẹ rẹ wa ka jọ wa bẹ Yeye Ọṣun ko ba wa fomi fọ arun Korona kuro lorileede wa, Gomina Oyetọla naa wa nipinlẹ Edo, nibi ti wọn ti gbemu-lemu o, o waa n sọ iye awọn to gbọdọ wa sodo, alawada lasan ni gbogbo wọn, ta lẹ ri to da wọn lohun bayii?

Bakan naa ni gbogbo awọn olubọ Ọṣun to ku ti a fọrọ wa lẹnu wo ṣe n sọ, koda, awọn agbofinro to wa nibẹ, to fi mọ awọn ọlọpaa, sifu difẹnsi, figilante, ajọ ẹsọ oju popo, awọn Amọtẹkun, wọn le ni ọgọrun-un, kan to wa, eyi ko yọ awọn ti wọn n ta ọti, ilẹkẹ, ike-omi, agbẹgilere, ounjẹ, adirẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ silẹ.

Aago mẹjọ kọja iṣẹju diẹ ni Arugba gbera laafin Ataọja, ọkẹ aimọye eeyan ni wọn si tẹle e titi de odo-Ọṣun, bẹẹ lonikaluku n sọ ẹdun ọkan rẹ, ti wọn si n taka oṣi ati aini danu. Dokita Ọbawale lo ṣoju Gomina Oyetọla nibẹ, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn si ko awọn awo sodi lọ sodo.

Ọbawale ṣalaye pe ki i ṣe pe ijọba mọ-ọn-mọ fẹẹ di awọn olubọ Ọṣun lọwọ, ṣugbọn koju ma ribi, gbogbo ara loogun rẹ lawọn fẹẹ fi ọrọ naa ṣe. O ni ijọba mọ pataki ọdun Ọṣun-Oṣogbo, idi niyẹn ti wọn fi n ṣatilẹyin fun igbelarugẹ ọdun naa ni gbogbo igba.

Araba Awo tiluu Oṣogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, naa ṣadura fun awọn olubọ Ọṣun, ilu Oṣogbo, ipinlẹ Ọṣun, orileede Naijiria ati gbogbo agbaye, o si ke pe Ọlọrun pe ko ba wa ka arun Korona kuro nilẹ, ki wọn le raaye ṣe ayẹyẹ ti ọdun to n bọ ninu ifọkanbalẹ.

Nigba ti aago meji ku diẹ ni Arugba kuro lodo, awọn eeyan si tun wọ tẹle e pada si aafin Ataọja.

Ọsẹ meji ni wọn fi maa n ṣe ayẹyẹ ọdun Ọṣun Oṣogbo. Lara awọn eto to maa n waye laarin ọsẹ meji yẹn ni Iwọpopo, ọdun-ade, titan atupa oloju mẹrindinlogun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Reply