O yẹ ki awọn to n gbe Buhari kiri lọdun 2015 tọrọ aforiji lọwọ gbogbo ọmọ Naijiria-Fayoṣe

Jide Alabi

Ọgbẹni Peter Ayọdele Fayoṣe, gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan, ti sọ pe gbogbo awọn ti wọn n gbe Buhari kiri lọdun 2015 pe oun lo yẹ nipo Aarẹ gbọdọ tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria bayii nitori ti wọn fi ọrọ ọkunrin naa ṣi awọn eeyan lọna.

Bi Aarẹ orilẹ-ede yii ṣe kọ lati yọju si awọn ọmọ ile-igbimọ aṣoju-ṣofin l’Ọjọbọ, Tọside, ̀ọsẹ  yii, lo mu Fayoṣe sọ pe ọwọ lile ni Buhari fi n sẹjọba, ati pe awọn to n gbe e kiri nigba naa lọhun-un ni wọn fi tiwọn ko ba Naijiria bayii.

Ni kete ti Aarẹ Buhari ti kọ lati yọju si wọn nile-igbimọ aṣoju-ṣofin ni Fayoṣe ti kọ ọ sori ikanni abẹyẹfo ẹ, nibi to ti ṣapejuwe Aarẹ orilẹ-ede yii gẹgẹ bii ẹni to n dari Naijiria bii igba to wa nipo ijọba ologun.

Fayoṣe ni, “Mo ti sọ ọ lọjọ kin-in-ni, oṣu kẹjila, ọdun yii, pe Buhari, ko ni i yọju si wọn nile aṣofin, nigba tawọn yẹn ke si pe ko waa ṣalaye ọna tijọba ẹ n gba nipa bi eto aabo ṣe ri loni-in ni Naijiria.”

“Iru ijọba Buhari yii ni mo ri ri o, Aarẹ alagbada ti ko bọwọ fun awọn ẹka eto iṣejọba mi-in, iru oloṣelu wo leeyan n pe iru wọn, bi ki i baa ṣe apaṣẹ-waa!’’

O ni pẹlu ọwọ ti Buhari fi n mu eto iṣakoso orilẹ-ede yii, niṣe lo yẹ ki awọn to n gbe e kiri lasiko ibo ọdun 2015 maa tọrọ aforiji bayii lọwọ gbogbo ọmọ Naijiria.

 

Leave a Reply