Faith Adebọla
Akọwe ijọba apapọ tẹlẹ ri, Ọgbẹni Babachir Lawal, ti ke si ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress lati wo gbogbo ilakaka agba-ọjẹ oloṣelu ilu Eko nni, Oloye Bọla Tinubu, lori ẹgbẹ oṣelu naa, ki wọn si fi ipo aarẹ ṣe ẹsan oore ti Tinubu ṣe ẹgbẹ ọhun, o ni ki wọn jẹ ki aarẹ to n bọ wa lati iha Guusu/Iwọ-Oorun orileede ti ilẹ Yoruba Yoruba wa.
Babachir sọrọ yii lọjọ Ẹti, Furaidee, niluu Abuja, lasiko to n sọ ero rẹ lori eto idibo gbogbogboo to n bọ ati ipo aarẹ lọdun 2023.
O ni Tinubu ti ṣe ọpọ gudugudu meje ati yaayaa mẹfa fẹgbẹ oṣelu APC sẹyin, o ni ọpẹlọpẹ akitiyan rẹ lo jẹ kẹgbẹ naa le jawe olubori ninu eto idibo 2015 ati tọdun 2019.
“Ki wọn too le yege ninu eto idibo to n bọ, ẹgbẹ oṣelu APC gbọdọ ṣeto iha ti wọn ti fẹ ki ondije funpo aarẹ ti wa, gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ofin ẹgbẹ. Iha Ariwa ti wa nipo aarẹ fọdun mẹjọ, iha Guusu lo kan bayii.
“Eekan gidi ni Tinubu ninu oṣelu ilẹ Yoruba, bọkunrin naa ba sọ pe ko ni i si ajọṣepọ pẹlu awọn ẹgbẹ oṣelu ti wọn so pọ lọdun 2014 ni, APC ko ni i yọju rara, debii pe wọn maa bọ sipo aarẹ.
“Bi Tinubu ṣe sọ p’oun maa ṣatilẹyin fun Buhari lasiko idibo abẹle ẹgbẹ naa lo ti han pe Buhari maa jawe olubori bii oludije ẹgbẹ, eyi lo si jẹ ki ọpọ ọmọ Yoruba ṣatilẹyin fun Buhari, bẹẹ ni Bisi Akande naa fọwọsowọpọ, eyi lo si jẹ ki awọn eeyan Oke-Ọya dibo fun Buhari yanturu. Ka ni Tinubu o juwọ silẹ fun Buhari ni, boya Kwankwaso ni iba jẹ oludije fẹgbẹ APC.
“Lero temi, pẹlu ohun ti Tinubu ti ṣe fẹgbẹ APC, paapaa lori ti Buhari yii, to jẹ pe ko lowo to le fi kampeeni tabi lọ kaakiri nigba yẹn, o yẹ ki ẹgbẹ naa mọyi oore Tinubu, ki wọn jẹ ki Yoruba mu aarẹ wa lọtẹ yii.”
Bẹẹ ni Babachir sọ.