Ọba di meji n’Ikire: Ile-ẹjọ yọ Ọba Falabi nipo

*N lawọn idile to kan ba jawe oye le Ọlanrewaju lori

*Idi ti a ko fi le kede yiyọ Akire tiluu Ikire – Ijọba Ọṣun

Florence Babaṣọla

Gbogbo oju lo wa lara ijọba ipinlẹ Ọṣun bayii lati mọ igbesẹ ti Gomina Gboyega Oyetọla fẹẹ gbe lori ọrọ ipo ọba ilu Ikire tile-ẹjọ giga ṣedajọ le lori lọsẹ to kọja.

Bi idile to da bii ẹni pe idajọ naa da lare ṣe sọ pe dandan kijọba ṣe nnkan ti ile-ẹjọ to ga ju lọ lorileede yii sọ lọdun 2014, eleyii tile-ẹjọ giga ilu Ikire tun kin lẹyin lọsẹ to lọja, naa ni Ọba Ọlatunde Falabi sọ pe ko si nnkan ti oun ṣe to fi yẹ kijọba yọ oun loye.

Bawo lọrọ ṣe jẹ gan an? Idile marun-un la gbọ pe o wa ninu akọsilẹ ilana to jade lọdun 1958 lori bi wọn yoo ṣe maa jẹ Akire, awọn idile naa ni Akẹtula, Ladekan, Lambẹloye, Desamu ati Oniṣọkan, nitori awọn maraarun-un ni wọn jẹ ọmọ Kuje ni ṣisẹ-n-tẹle.

Loootọ, wahala kan waye nigba kan laarin wọn, eleyii to mu kijọba igba naa gbe igbimọ oluwadii kan ti wọn pe ni Ọbasa Commission of Enquiry kalẹ lori ọrọ awọn to lẹtọọ si ipo Akire.

Lara aba ti igbimọ naa funjọba ni pe idile Akẹtula ko yẹ ko wa lara awọn ti wọn aa maa jẹ Akire, ṣugbọn fun idi ti ẹnikẹni ko mọ, ijọba igba yẹn ko sọ aba naa di aṣẹ.

Nigba ti Akire ana to wa lati idile Onisọkan, Ọba Oseni Oyegunlẹ, waja lọdun 1987, awọn afọbajẹ bẹrẹ igbesẹ jijẹ Akire tuntun, gbogbo idile si fi ọmọ oye silẹ. Ọmọọba Tajudeen Ọlanrewaju ni idile Akẹtula fi silẹ nigba naa gẹgẹ bii idile ti ipo naa kan. Ṣugbọn awọn kan tun lọ si kootu lori abọ iwadii Ọbasa Commission of Enquiry, eleyii ni wọn n ṣe lọwọ tijọba fi gbe ọpa-aṣẹ fun Ọba Ọlatunde Falabi lati idile Lambẹloye.

Bayii ni ẹjọ bẹrẹ ni pẹrẹu, Ọmọọba Tajudeen Ọlanrewaju atawọn idile rẹ ṣe ẹjọ yii titi de ile-ẹjọ to ga ju lọ lorileede Naijiria, adajọ si dajọ lọjọ kọkanla, oṣu kẹrin, ọdun 2014, pe idile Akẹtula lẹtọọ sipo Akire, koda, ibẹ ni oye kan, nitori oun lo wa nipele akọkọ ninu ilana ọdun 1958.

Wọn mu idajọ lọ sọdọ ijọba ipinlẹ Ọṣun nigba naa, ṣugbọn lasiko tijọba n yẹ idajọ naa wo lọwọ ni Ọba Ọlatunde lọ si ile-ẹjọ giga ilu Ikire lati lọ ka ijọba lọwọ ko lori idajọ naa.

Eleyii ni Adajọ kootu naa, Abdulrasaq Kareem, ṣedajọ le lori lọsẹ to kọja, to si da gbogbo ẹbẹ ti Ọba Falabi gbe lọ nu lẹyọkọọkan.

Ọba Falabi sọ pe ki ile-ẹjọ ka ijọba ipinlẹ Ọṣun, kọmisanna feto-idajọ ati kọmisanna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ lọwọ ko, ki wọn ma ṣe yọ oun nipo niwọn igba ti oun ko ṣe nnkan tiru igbesẹ bẹẹ fi tọ si oun.

Bakan naa ni Ọba Falabi sọ pe kile-ẹjọ da ijọba duro lori igbesẹ yiyan Akire tuntun fun ilu Ikire tori a ki i fọba mi-in jẹ ti ọba kan ko ba gbesẹ

Ṣugbọn Onidaajọ Karem sọ pe oun ko lagbara lati di ẹka ijọba mi-in lọwọ lori ohun to ba tọna lati ṣe nilana ofin. O ni idajọ ile-ẹjọ to ga ju lọ lorileede yii ti ọdun 2014 ti fidi rẹ mulẹ pe ile marun-un lo lẹtọọ si ori aga Akire.

O ni loootọ ni igbimọ Ọbasa Commission of Enquiry dabaa pe kijọba yọ orukọ idile Akẹtula, ko si ẹku idile Ladekan, Lambẹloye, Desamu ati Oniṣọkan, ṣugbọn ijọba ko sọ aba naa di ofin nigba yẹn.

Adajọ fi kun idajọ rẹ pe idajọ ọdun 2014 ti fagi le iyansipo Ọba Falabi, nitori pe ki i ṣe idile Akẹtula ti oye kan lo ti wa.

Pẹlu idajọ yii, agbẹjọro fun awọn afọbajẹ ilu Ikire, Adeboye Shobanjọ sọ fawọn oniroyin pe ile-ẹjọ ko sọ taara pe ki wọn yọ Ọba Falabi loye, ṣugbọn agbẹjọro fun Ọmọọba Ọlanrewaju sọ ni tiẹ pe kedere lo han ninu idajọ pe Ọba Falabi ko le duro lori ipo yẹn.

Bi kootu ṣe pari lọjọ naa lawọn kan ti ja ewe akoko le Ọmọọba Tajudeen Ọlanrewaju lori gẹgẹ bii Akire ti ilu Ikire tuntun, to si yọ ori jade ninu mọto titi to fi wọnu ilu.

Nigba to n sọrọ lori idajọ naa, akọwe agba fun ileeṣẹ eto idajọ nipinlẹ Ọṣun  (Solicitor-General and Permanent Secretary) Barista Dapọ Adeniji, ṣalaye pe loootọ nidajọ kan wa tẹlẹ pe kijọba yọ Ọba Falabi, ṣugbọn ko si ẹnikankan to ṣiṣẹ tọ ọ lẹsẹ.

Adeniji ṣalaye pe nigba ti Ọba Falabi lọ si kootu lati da idajọ naa duro lawọn olupẹjọ akọkọ naa too ji giri nipa idajọ ti wọn ni lọwọ.

Amọ ṣa, Adeniji sọ pe lori idajọ ti ọsẹ to kọja yii, ijọba iba ti gbe igbesẹ, ṣugbọn Ọba Falabi ti fun ijọba ni iwe pe oun ti gbe ẹjọ naa lọ sile-ẹjọ kotẹmilọrun, niwọn igba ti ofin si gba a laaye lati ṣe bẹẹ, ohun gbogbo yoo duro daari na lori ẹ.

Ni ti Ọmọọba Tajudeen Ọlanrewaju, o sọ fun ALAROYE lopin ọsẹ to kọja pe, “Lẹyin ti ile-ẹjọ ti dajọ lọjọ Mọnde, ọjọ kọkanlelogun, a n reti ki a gba atẹjade (copies) idajọ yẹn, ki a le lọ mu un ba ijọba ipinlẹ Ọṣun lati fi ọwọ si i pe Ọba Ọlatunde ko lẹtọ sibi to wa.

“Iwe idajọ yẹn lo n da wa duro, o yẹ kijọba ti gbe igbesẹ lori ẹ, nitori ohun ti ile-ẹjọ giga ju lọ lorileede yii sọ sẹyin lọdun 2014 nidajọ yẹn tun kin lẹyin, kijọba sọrọ jade lo ku. Ṣugbọn a ko mọ nnkan to de ti wọn fi n da igbesẹ wọn duro, ṣe ẹ mọ pe ko sibi ti oṣelu ki i wọ, ṣugbọn awa ni i lọkan pe iwe idajọ ti a ko ti i fun wọn lo fa idaduro”

ALAROYE beere boya ẹnikẹni ti ranṣẹ si baba ẹni ọdun mẹtalelọgọta naa lẹyin idajọ, o ni, ‘ẹnikẹni o pe mi o, ki ni wọn fẹẹ bẹ mi fun? Latidile Akẹtula ni mo ti wa, latilẹ la ti wa lara idile to n jọba niluu Ikire, nọmba kẹta ni idile Lambẹloye ti Baba Falabi ti wá wà, nigba ti Akẹtula wa ni nọmba kin-in-ni, idile Akẹtula ni oye yẹn dẹ kan nigba yẹn.

Leave a Reply