Ọba fẹ Ọmọọba:Oluwoo ilẹ Iwo ṣegbeyawo pẹlu Ọmọọba Kano

Florence Babaṣọla, Osogbo

Oni ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta yii, ni ayẹyẹ igbeyawo Oluwoo tilẹIwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi, n waye niluu Kano.

Bo tilẹ jẹ pe gẹgẹ bii aṣa, ọba alade naa ko ni i yọju sibi igbeyawo ọhun, niṣe ni wọn yoo mu Olori waa ba Kabiyesi lẹyin ti eto gbogbo ba ti pari niluu Kano.

Ogunjọ, oṣu yii, ti i ṣe ọjọ Aiku, ni wọn yoo mu Oori Firdauz, Adewale Akanbi waa ba wọn laafin ọba.

Leave a Reply