Ọba ilu Ipokia kilọ fawọn aṣọbode, o ni ki wọn yee pa awọn eeyan oun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọba Yisa Ọlaniyan, Onipokia ti Ipokia nipinlẹ Ogun, ti kilọ fawọn aṣọbode ti wọn yi agbegbe rẹ ka lati dawọ ipaniyan to n waye nigba gbogbo duro. Ọba ni ẹgbẹrun kan apo irẹsi ti wọn n tori ẹ yinbọn paayan ko to ẹmi eeyan kan ṣoṣo.

Ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii ni Onipokia ṣe ikilọ naa fun alakooso ẹkun kin-in-ni kọstọọmu nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Peter Kolo, nigba ti ọkunrin naa ṣabẹwo si i niluu Ipokia.

Sọ fawọn eeyan rẹ ki wọn yee pa awọn araalu mi nitori irẹsi, ẹgbẹrun kan apo irẹsi ko to ẹmi eeyan kan ṣoṣo. Ki i ṣe pe mo faramọ fayawọ ṣiṣe, ṣugbọn mi o le gba ki ẹmi awọn eeyan mi maa bọ laiṣẹ nitori apo irẹsi lasan.’ Bẹẹ ni Onipokia wi.

Nigba to n dahun si ọrọ Kabiyesi, ọga kọsitọọmu naa sọ pe oun naa ko fẹran ipaniyan, bẹẹ lawọn eeyan oun ki i deede lo nnkan ija, afi ti ọrọ ba fẹẹ ba eyin yọ.

Kolo fi Kabiyesi lọkan balẹ, o loun ko ni i gba ki ẹmi alaiṣẹ sọnu mọ nitori irẹsi bo ṣe maa n waye.

Ṣe lọpọ igba lẹmi awọn ti ko tiẹ mọ nnkan kan nipa fayawọ maa n sọnu n’Ipokia, lasiko tawọn kọstọọmu atawọn onifayawọ ba wọya ija. Aimọye awọn ti ko mọwọ-mẹsẹ ni wọn ti ba ogun irẹsi lọ.

 

Leave a Reply