Ọba Oniranike pariwo: Bi ohunkohun ba ṣẹlẹ si mi laburu, Ewusi Makun ni kẹ ẹ mu o

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

O tojọ mẹta ti ọrọ ilẹ ti n fa ariyanjiyan laarin Ọba Adewale Adeniji ( Oniranikẹn ni Ṣagamu),ati awọn eeyan ilẹ Ewusi Makun, ni Ṣagamu kan naa. Ọrọ ilẹ ohun lo gbọna mi-in yọ bayii, ti Oniranikẹn fi n kegbajare, pe bi aburu kan ba ṣẹlẹ soun pẹnrẹn lasiko yii, Ọba Timothy Oyeṣọla Akinsanya, Ewusi Makun, ni kijọba atawọn araalu mu si i.

Niṣe ni Oniranikẹn pepade awọn akọroyin lọjọ Satide to kọja yii, to ni ki wọn ba oun gbe e saye pe lọjọ kẹjọ, oṣu kẹrin yii, lọwọ oru, ni awọn kan wọ aafin oun wa ti wọn n wa oun kiri.

Kabiyesi sọ pe lori ọrọ ilẹ to ju ẹgbẹrun mẹrin eeka tawọn Makun n ba oun ja si ni wọn n wa oun fun.

O ni ọrọ ilẹ naa loun si ba lọ s’Ekoo, nigba to ti di ẹjọ. Afi bawọn janduku naa ṣe bẹrẹ si i lu iyawo oun, nigba ti wọn ko ri oun nile. Ti wọn ba ọpọlọpọ dukia oun jẹ, ti wọn tun gba owo to to ẹgbẹrun lọna irinwo (400,000) lọwọ Olori atawọn eeyan mi-in laafin oun.

Oniranikẹn sọ pe ọjọ meje ni awọn eeyan Makun foun lati yọnda ilẹ ti ile-ẹjọ ti da mọlẹbi oun lare lori ẹ, ọjọ ti ọjọ meje naa si pe ni wọn waa kọ lu aafin oun yii. O ni to ba jẹ pe wọn ba oun nile ni, boya ohun ti a n wi yii kọ la ba maa wi.

‘‘Mi o le rin pẹlu ifọkanbalẹ mọ, tifura-tifura ni mo n rin ki wọn ma baa ṣe mi leṣe. Bẹẹ, emi nikan kọ ni ile-ẹjọ yọnda ilẹ yii fun, ilẹ mọlẹbi wa ni. Ṣugbọn Ewusi Makun n ran awọn eeyan ẹ lati maa pariwo ole le mi lori, wọn jawe dani loju titi, wọn n ba orukọ mi jẹ loju iwe iroyin, wọn tun waa da aafin mi ru. Bi ohunkohun ba ṣẹlẹ si mi laburu, Ewusi Makun ni kẹ ẹ mu si i o.’’

Nigba to n dahun ibeere pe ṣe ọrọ ilẹ ti wọn n fa yii ko ni i di rogbodiyan siluu bayii, Oniranikẹn sọ pe oun ti kilọ fawọn eeyan oun lati ma ṣe da wọn lohun tabi ba wọn ja, o ni wọn ko gbọdọ jawe kiri ilu bii awọn Makun. O ni bi wahala kankan ba ṣẹlẹ, aa jẹ pe awọn Makun ni wọn n da fa a.

Lọọya to ba Oniranikẹn gbadajọ lori ilẹ yii lọdun 2018, Amofin Babatunde Ọshilaja ati Lọọya Kọle Oyedele, wa nikalẹ nibi ipade naa. Ohun ti wọn sọ ni pe awọn Makun ti tẹ ẹtọ Oniranikẹn mọlẹ, wọn ti tapa sofin ile-ẹjọ, ko si ni i buru ju kawọn naa fọwọ ofin ba wọn ja, bi wọn ko ba tete kọwọ ọmọ wọn bọṣọ.

Wọn ni kijọba Gomina Dapọ Abiọdun tete gbe igbimọ ododo ti yoo yanju ọrọ yii kalẹ, yatọ si tile- igbimọ aṣofin Ogun tawọn Makun gbejọ lọ.

Ẹ oo ranti pe ọsẹ to kọja lọhun-un lawọn Makun ko ẹjọ lọ si Aafin Ọba Babatunde Adewale Ajayi, Akarigbo ilẹ Rẹmọ, pe ko paṣẹ fun Oniranikẹn pe ko kuro lori ilẹ eeka rẹpẹtẹ to fi awọn ajagungbalẹ gba lọwọ abule mẹrinla, ti i ṣe ti Makun.

Ṣugbọn Oniranikẹn sọ pe ile-ẹjọ giga ti dajọ naa lọdun 2018, wọn da mọlẹbi oun lare, nitori ilẹ awọn nilẹ naa. O loore lawọn ṣe fun Makun nipa gbigba wọn lalejo, ko too di nnkan mi-in lasiko yii, ti wọn waa n lepa ẹmi ọba ti ko ṣẹ wọn.

ALAROYE gbiyanju lati gbọ ọrọ lẹnu Ewusi Makun, ṣugbọn ko bọ si i. Adele akọwe ajọ Ewusi (Ewusi–in-Council),Ọtunba Kayọde Howells, lo ṣalaye fun wa pe irọ buruku ni gbogbo ohun ti Oniranikẹn sọ. O ni ibajẹ lasan lawọn ẹsun naa, Oniranikẹn kan fẹẹ fi gba ojuure ni.

Howells sọ pe Ewusi Makun toun mọ ki i ṣe oniwahala, ko si si idi kan fun un lati maa lepa ẹmi ẹnikẹni kiri.

Leave a Reply