Ibrahim Alagunmu, Ilorin
Ọjọ Ẹti, Fridee, ọṣẹ yii, ni wọn kede pe Ọba Oludọfian ti ilu Idọfian, nipinlẹ Kwara, Ọba Subair Agboola Adeyẹye Oyesoro keji, ti waja, lẹyin ọdun mẹrindinlọgọta (56) lori apere.
ALAROYE gbọ pe, Ọba Adeyẹye ni ọba to dagba ju lọ ninu gbogbo awọn ọba alaye to wa nipinlẹ Kwara, ko too di pe o dagbere faye. Ninu oṣu karun un, ọdun (1965) lo gori apere baba to bi i lọmọ, to jọba ilu Idọfian, o papoda ni owurọ kutukutu ọjọ Ẹri, Furidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹfà, ọdun yii. Ọdun mẹrindinlọgọta (56) lo lo lori oye.