Florence Babaṣọla
Aarẹ orileede yii tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti ṣapejuwe Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Goyega Oyetọla, gẹgẹ bii ọmọluabi tootọ, to si ni iwa irẹlẹ pupọ.
Lasiko ti Ọbasanjọ ṣabẹwo sọdọ Oyetọla nile ijọba, niluu Oṣogbo, nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ ta a lo tan yii lo ni o ti pẹ toun ti de ile ijọba ipinlẹ Ọṣun, ṣugbọn oun pinnu lati ya nitori pe gomina to wa nibẹ bayii jẹ ẹni to lafojusun rere.
A gbọ pe ilu Okuku, nibi ti wọn ti fi Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla jẹ oye baba-ijọ Ọba Moses Oyinlọla Memorial Anglican Church, ni Oloye Ọbasanjọ ti n bọ to fi ya sọdọ Gomina Oyetọla.
Ọbasanjọ ṣalaye pe ẹni to mọ bi a ṣe n ṣakoso eeyan, to si lafojusun rere pẹlu iwọnba nnkan to n wọle sipinlẹ Ọṣun ni Oyetọla, iṣejọba rẹ si fi i han gẹgẹ bii ẹni to mọ nnkan to n ṣe.
Ninu ọrọ rẹ, Oyetọla, ẹni ti iyawo rẹ, Alhaja Kafayat Oyetọla, duro ti, dupẹ lọwọ Oloye Ọbasanjọ fun abẹwo naa, o ni iwuri nla lo jẹ fun oun ati pe yoo tun ran oun lọwọ lati tẹ siwaju ninu iṣẹ rere to n ṣe nipinlẹ Ọṣun.