Ọbasanjọ ṣe tẹẹsi Koro, wọn ni baba ko ni Koro o

Ẹbọra Owu, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, naa ti ṣayẹwo Korona o. Aarẹ ilẹ wa tẹlẹ naa ti ni kawọn dokita waa yẹ oun wo boya oun ni arun aṣekupani Koronafairọọsi lara tabi oun wa kampe.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, ni Dokita Olukunle Ọlasemowo lati ọsibitu ti wọn ti n ṣe ayẹwo, Molecular Genetics Laboratory, niluu Eko, eyi  ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ arun ati kokoro (NCDC), fọwọ si lọọ ṣe ayẹwo fun Baba Iyabọ nile rẹ to wa ni  Oluṣẹgun Ọbasanjọ Presidential Library, (OOPL), ni Oke Mọsan, l’Abẹokuta.

Ọjọ Abamẹta, Ṣatide, ọsẹ ta a lo tan yii ni esi naa jade. Ṣugbọn ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni Akọwe iroyin fun aarẹ tẹlẹ ọhun, Kẹhinde Akinyẹmi, sọ iroyin naa di mimọ.

O ni Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti ṣe tẹẹsi Koro, ṣugbọn baba ko ni Koro, gẹgẹ bi ayẹwo naa ti ṣe fi han.

Leave a Reply