Ọlawale Ajao, Ibadan
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ṣabẹwo si ọba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan niluu Ibadan, Agba-oye Lekan Balogun.
Nile rẹ to wa ni Alarere, ni Ẹbọra Owu bi wọn ṣe tun maa n pe baba naa ti yọju si ọba ti wọn ṣẹṣẹ yan ọhun. O ki i ku oriire bi wọn ṣe yan an gẹgẹ bii Olubadan ilẹ Ibadan kejilelogoji. Bẹẹ lo gbadura fun ẹmi gigun ati ilera pipe ti yoo fi lo ipo naa.
Ọbasanjọ ni o da oun loju pe pẹlu oriṣiiriṣii iriri ti ọba tuntun yii ti ni, ilu Ibadan yoo tete ni idagbasoke ti yoo ya kankan lasiko ijọba rẹ.