Ọbasanjọ ati Buhari pade lori ẹrọ ayelujara

Jide Kazeem

Awọn olori ilẹ wa tẹlẹ, Olusẹgun Ọbasanjọ ati Yakubu Gowon, Earnest Ṣhonekan ati Abdulsalam Abubakar  ti n ṣepade pọ pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari lori ẹrọ ayelujara.

Bo tilẹ pe ilu Abuja ni Buhari wa ni tiẹ to ti n ba wọn ṣepade yii, ori ẹrọ ayelujara lawọn olori ile wa telẹ naa ti n ba a sọrọ, nibẹ ni ipade naa ti n lọ lọwọ ba a ṣe n sọ yii.

Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to ti i le sọ ohun ti ipade naa da le lori, ṣugbọn awọn to mọ bo ṣe n lọ sọ pe ipade naa ko sẹyin rogbodiyan to n lọ nilẹ wa, nibi ti awọn ṣọja ti ṣina ibọn fun awọn ọdọ to n ṣewọde jẹẹjẹ wọn.

One thought on “Ọbasanjọ ati Buhari pade lori ẹrọ ayelujara

Leave a Reply