Ọbasanjọ foju bale-ẹjọ, ẹni to ṣoniduuro fun l’Oṣogbo lo sa lọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Kootu Majisreeti kan niluu Oṣogbo lawọn ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun wọ Adeṣiyan Ọbasanjọ lọ lori ẹsun pe ẹni to ṣoniduuro fun sa lọ fun iwadii awọn ọlọpaa.

Ọjọ kẹjọ, oṣu keje, ọdun yii, ni Ọbasanjọ duro fun Yẹye Bukọla, ẹni to parọ gbowo, to si tun fi sọwe-dowo ti ko si owo kankan ninu ẹ silẹ lagọọ ọlọpaa to wa ni Dugbẹ, niluu Oṣogbo.

Inspẹkitọ Adeoye Kayọde to jẹ agbefọba ṣalaye funle-ẹjọ pe Ọbasanjọ ṣeleri fawọn ọlọpaa pe oun yoo mu Bukọla pada sọdọ wọn lọjọ keji, ati ni gbogbo ọjọ ti wọn ba fẹẹ ri i titi ti ẹjọ naa yoo fi pari.

Ṣugbọn ṣe ni ọkunrin yii mọ si bi Bukọla ṣe sa kuro nipinlẹ Ọṣun, ti eleyii si ṣe idiwọ nla fun iwadii awọn ọlọpaa lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Lẹyin ti Ọbasanjọ sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an ni agbẹjọro rẹ, Okobe Najite, bẹbẹ fun beeli rẹ lọna irọrun, ṣugbọn agbefọba ta ko arọwa naa, o ni latinu oṣu keje ni Bukọla ti sa lọ sipinlẹ Ogun, ti awọn ọlọpaa si ṣe wahala pupọ ki wọn too ri oniduuro rẹ, Ọbasanjọ, mu.

 

Majisreeti A. A. Adeyẹba fun olujẹjọ ni beeli pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (#500,000) ati oniduuro meji.

Leave a Reply