‘‘Ọbasanjọ ko lẹnu ọrọ nipa bi ṣoja sẹ kọ lu araalu ni Lẹkki’’

Jide Kazeem

Awọn eeyan Odi, nipinlẹ Bayelsa, ti n binu si Ọbasanjọ o, ẹsun ti wọn si fi kan an ni pe ki i ṣe iru ẹ lo yẹ ko maa ba ijọba kan wi nitori to ko ṣoja kọ lu awọn araalu.

Ninu atẹjade ti Igbakeji ọba ilu naa, Oloye Prenus Ogboin, olori awọn ọdọ, Ikposuoeski Inemike, ati alaga idagbasoke ilu naa, Goddey Niweigha, fọwọ si ni won ti sọ pe Obasanjọ gbọdọ tọrọ aforiji lọwọ awọn eeyan Odi nitori adanu nla to ko ba wọn lọdun 1999 to fi awọn ṣoja pa ilu naa run.

Awọn aṣaaju ilu Odi yii ti sọ pe gbogbo ilu naa ko ni i gbagbe bi Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ṣe ko awọn ṣọja ja ilu yii, ti wọn si sọ gbogbo ilu dahoro.

Wọn ni awọn ọdọ kan ni wọn jade ifẹhonu han lati ta ko bi ijọba ṣe n wa epo niluu Odi, nipinlẹ Bayelsa, ṣugbọn niṣe nijọba Ọbasanjọ sọ ọ di wahala mọ wọn lọwọ, ti ọpọ ẹmi si ṣofo rẹpẹte nigba tawọn ṣoja to yẹ ko maa sọ araalu kogun ja wọn.

Wọn ti ni ki Ọbasanjọ tọrọ aforiji lọwọ gbogbo awọn eeyan ilu Odi, nitori lojoojumọ ni ibanujẹ ọkan awọn n pọ si i lori iṣẹlẹ ọhun.

Leave a Reply