Ọbasanjọ ni Buruji Kaṣamu sa fawọn ọlọpaa aye, ṣugbọn ko le sa fawọn ọlọpaa ọrun

Aarẹ orilẹ-ede yii nigba kan, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti fi oko ọrọ ranṣẹ si oloṣelu ipinlẹ Ogun to ṣẹṣẹ jade laye yii, Oloye Ẹṣọ Jinadu ti wọn n pe ni Buruji Kaṣamu, lọna ọrun. O ni Buruji sa fawọn ọlọpaa aye, ṣugbọn ko le sa fawọn ọlọpaa ọrun, titi ti wọn fi mu un lọ.

Ninu lẹta ibanikẹdun ti Ọbasanjọ kọ si Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ naa lo ti ṣalaye awon ọrọ yii. O ni, “Gomina, mo ba ọ kẹdun fun ti iku ọkan pataki ninu awọn ọmọ ipinlẹ wa, Ẹṣọ Jinadu (Buruji Kaṣamu), to jade laye lojiji. Ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rere.

“Iku Ẹṣọ Jinadu yii gbọdọ je ikilọ fun gbogbo awọn oloṣelu wa, ati ohun  ti wọn yoo maa ranti ni gbogbo igba ti wọn ba n hu awọn iwa wọn. Ẹsọ Jinadu, nigba aye rẹ, sa fun awọn ọlọpaa ti wọn n wa a lati mu fun awọn iwa ọdaran to hu nilẹ wa nibi, ati awọn ọlọpaa ilu oyinbo ti wọn fẹe mu un lọ sọhun-un fun iwa ọdaran mi-in to hu lọdọ wọn. Ṣugbọn nigba ti awọn ọlọpaa Ọlọrun de ti wọn fẹẹ mu un, Ẹsọ jinadu ko ri ibi kankan to le sa lọ. Ki Ọlọrun fi Alujanna ta a lọre o.”

Bẹẹ ni Oluṣẹgun Ọbasanjọ kọwe rẹ si Gomina, nipa ti Ẹṣọ Jinadu to lọ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Pasitọ Chibuzor fun awọn obi Deborah ni ile fulaati mẹrinla atawọn ẹbun mi-in

Monisọla Saka O da bii pe iku Deborah, ọmọbinrin ti awọn awọn kan juko pa, …

3 comments

  1. Christana Abimbola

    Ki olorun te won si afefe rere, ki o pa asise re re

  2. Yoruba feran agbo sodi oro, ninu alaye ninu leta wonyi, emi kori oko oro kankan nibe bi kiise agbo sodi

  3. Baba obasanjo eyin gan fun rarayin, u will die one day with all d money u steel and d all corruption u made, remember u will die one day, u r d father of corruption

Leave a Reply

//unbeedrillom.com/4/4998019
%d bloggers like this: