Olori orilẹ-ede yii nigba kan, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti sọ iye ọdun to wu oun lati lo laye o. Ọbasanjọ ni o wu oun ki oun lo ju ọgọrun-un ọdun laye lọ. O ni bo ba ri bẹẹ, oun yoo tubọ le maa ba Agura ilu Gbagura, Oba Sabur Bakare, Jamolu Keji, ṣe ayẹyẹ ọdun igbade gbogbo to ba n ṣe.
Ilu Abẹokuta ni Ọbasanjọ ti n sọrọ yii, nigba ti Ọba Bakare n ṣe ayẹyẹ ọdun kan to gbade gẹgẹ bii Agura ti Gbagura, to si ko ọpọlọpọ awọn eeyan nla-nla ilu jọ. Nibẹ ni Ọbasanjọ ti sọ pe ayẹyẹ ọdun kan ti Agura gbade ni oun waa ba a ṣe yii o, ṣugbọn lẹyin ti oun ba waa ba ọba naa ṣe ayẹyẹ ogun ọdun to gbade, Ọlọrun le mu oun sọdọ nigba naa, nitori oun yoo ti le ni ọmọ ọgọrun-un ọdun daadaa.
Ninu oṣu karun-un ọdun 2019 to kọja yii ni Ọba Bakare gbade, o di ọdun 2039 ko too ṣe ayẹyẹ ogun ọdun to gbade, Ọbasanjọ si fẹ ki oun wa laye ju igba naa lọ, bi Ọlọrun ba fẹ.
Olorun a ran baba l’owo lati lo ju be lo o.
Olorun ni lo mo igba ati Akoko eniyan