Ọbasanjọ tun gba Buhari nimọran, o lo dara ko ṣe ohun tawọn ọdọ n fẹ

Jide Kazeem

Aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti ke si Muhammad Buhari ko tẹti si awọn ọdọ, ki rogbodiyan iwọde ta ko ẹṣọ agbofinro SARS to wa lode yii le kasẹ nilẹ patapata.
Ni Ile Ifẹ, laafin Ọọni Ifẹ, Ọba Ẹnitan Ogunwusi, ni Ọbasanjọ ti sọrọ yii lọjọ Aje, Mọnde,ọsẹ yii. O ni ọpọ anfaani ni Aarẹ Muhammad Buhari ni lati fi i han gẹgẹ bíi olori orilẹ-ede to mọ idojukọ tawọn ọdọ n ni.
Aarẹ tẹlẹ yii ni ida marundinlaaadọrin awọn eeyan orilẹ-ede yii ni ọjọ orí wọn jẹ bii ẹni ọdun mẹrindilogoji, ati pe ninu awọn eeyan ti wọn jẹ ọdọ yii ni wọn tiraka lati kawe, bẹẹ lawọn mi-in paapaa ko ri iwe ọhun ka, ti awọn to sì ka a pàápàá ko tun riṣẹ gidi fi ṣe.
Ọbasanjọ waa sọ pe asiko niyi lati wa ojuutu to yẹ sawọn ibi tọrọ ku si yii. Bakan naa lo sọ pe oun mọ daadaa pe abiyamọ ni Buhari naa, to si ni awọn ọdọ, ati pe o mọ bi awọn ọdọ ṣe maa n ṣe, o si gbọdọ lọ ọpọ anfaani to wa nilẹ bayii lati fi wa ojuutu sọrọ to wa nilẹ yii .

Leave a Reply